Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 27:7 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 “Ohun tí àwọn ọmọbìnrin Ṣelofehadi ń sọ tọ̀nà. Ogbọdọ̀ fún wọn ní ogún ìní ti baba wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

7 “Ohun tí àwọn ọmọbinrin Selofehadi bèèrè tọ́, fún wọn ní ilẹ̀ ìní baba wọn láàrin àwọn eniyan baba wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Awọn ọmọbinrin Selofehadi sọ rere: nitõtọ, fun wọn ni ilẹ-iní kan lãrin awọn arakunrin baba wọn; ki iwọ ki o si ṣe ki ilẹ-iní baba wọn ki o kọja sọdọ wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 27:7
10 Iomraidhean Croise  

Àti ní gbogbo ilẹ̀ náà, a kò rí obìnrin tí ó ní ẹwà bí ọmọ Jobu; baba wọ́n sì pínlẹ̀ fún wọn nínú àwọn arákùnrin wọn.


Baba àwọn aláìní baba àti onídàájọ́ àwọn opó ni Ọlọ́run ní ibùgbé rẹ̀ mímọ́


Fi àwọn ọmọ aláìní baba sílẹ̀ èmi yóò dáàbò bo ẹ̀mí wọn. Àwọn opó rẹ gan an lè gbẹ́kẹ̀lé mi.”


Olúwa sì wí fún un pé,


“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, ‘Tí ọkùnrin kan bá kú tí kò sì fi ọmọkùnrin sáyé, ẹ fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ní ogún ìní rẹ̀.


Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa, Mose pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé: “Ohun ti ẹ̀yà àwọn ìran Josẹfu ń sọ tọ̀nà.


Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ fún àwọn ọmọbìnrin Ṣelofehadi: Wọ́n lè fẹ́ ẹni tí ọkàn wọn fẹ́, kìkì pé wọ́n fẹ́ nínú ẹ̀yà ìdílé baba wọn.


Kò le sí Júù tàbí Giriki, ẹrú tàbí òmìnira, ọkùnrin tàbí obìnrin nítorí pé ọ̀kan ni nínú Kristi Jesu.


Wọ́n sì lọ bá Eleasari àlùfáà, Joṣua ọmọ Nuni, àti àwọn olórí wí pé, “Olúwa pàṣẹ fún Mose láti fún wa ní ìní ní àárín àwọn arákùnrin wa.” Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua fún wọn ní ìní pẹ̀lú àwọn arákùnrin baba wọn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan