Numeri 27:11 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní11 Tí baba rẹ̀ kò bá ní arákùnrin, fún ará ilé rẹ̀ tí ó bá súnmọ́ jù ní ìdílé rẹ̀ ní ogún ìní rẹ̀, kí ó lè jogún rẹ̀. Èyí gbọdọ̀ jẹ́ ìlànà ìdájọ́ fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.’ ” Faic an caibideilYoruba Bible11 Bí baba rẹ̀ kò bá ní arakunrin, ẹ fi ilẹ̀ ìní rẹ̀ fún ìbátan rẹ̀ tí ó bá súnmọ́ ọn jùlọ ninu ìdílé rẹ̀. Ìbátan rẹ̀ yìí ni yóo jogún rẹ̀. Èyí yóo máa jẹ́ ìlànà fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.” Faic an caibideilBibeli Mimọ11 Bi baba rẹ̀ kò ba si lí arakunrin, njẹ ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní rẹ̀ fun ibatan rẹ̀, ti o sunmọ ọ ni idile rẹ̀, on ni ki o jogún rẹ̀: yio si jasi ìlana idajọ fun awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. Faic an caibideil |