Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 26:9 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 àwọn ọmọkùnrin Elifelehu ni Nemueli àti Eliabu, Datani àti Abiramu. Èyí ni Datani àti Abiramu náà tí wọ́n ní òkìkí nínú ìjọ tí ó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ sí Mose àti Aaroni tí ó sì wà lára àwọn ẹgbẹ́ Kora nígbà tí wọ́n bá Olúwa jà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 Eliabu bí Nemueli, Datani ati Abiramu. Datani ati Abiramu yìí ni wọ́n jẹ́ olókìkí eniyan láàrin àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ni wọ́n bá Mose ati Aaroni ṣe gbolohun asọ̀ nígbà tí Kora dìtẹ̀, tí wọ́n tako OLUWA.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Ati awọn ọmọ Eliabu; Nemueli, ati Datani, ati Abiramu. Eyi ni Datani ati Abiramu na, ti nwọn lí okiki ninu ijọ, ti nwọn bá Mose ati Aaroni jà ninu ẹgbẹ Kora, nigbati nwọn bá OLUWA jà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 26:9
5 Iomraidhean Croise  

Ilẹ̀ la ẹnu ó sì gbé Datani mì ó bo ẹgbẹ́ Abiramu mọ́lẹ̀


Àwọn wọ̀nyí ni wọ́n yàn nínú àwùjọ ènìyàn, olórí àwọn ẹ̀yà baba wọn. Àwọn ni olórí àwọn ẹbí Israẹli.


Àwọn ọmọkùnrin Pallu ni Eliabu,


Ègbé ni fún wọn! Nítorí tí wọ́n ti rìn ní ọ̀nà Kaini, wọ́n sì fi ìwọra súré sínú ìṣìnà Balaamu nítorí ère, wọn ṣègbé nínú ìṣọ̀tẹ̀ Kora.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan