Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 26:59 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

59 Orúkọ aya Amramu sì ń jẹ́ Jokebedi, ọmọbìnrin Lefi, tí ìyá rẹ̀ bí fún Lefi ní Ejibiti. Òun sì bí Aaroni, Mose, àti Miriamu arábìnrin wọn fún Amramu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

59 Orúkọ aya Amramu ni Jokebedi, ọmọbinrin Lefi tí ìyá rẹ̀ bí fún Lefi ní Ijipti. Ó bí Aaroni ati Mose ati Miriamu, arabinrin wọn fún Amramu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

59 Orukọ aya Amramu a si ma jẹ́ Jokebedi, ọmọbinrin Lefi, ti iya rẹ̀ bi fun Lefi ni Egipti: on si bi Aaroni, ati Mose, ati Miriamu arabinrin wọn fun Amramu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 26:59
7 Iomraidhean Croise  

Miriamu wòlíì obìnrin, arábìnrin Aaroni, mú ohun èlò orin ni ọwọ́ rẹ̀, gbogbo àwọn obìnrin sì jáde tẹ̀lé e pẹ̀lú ìlù òun ijó.


Arábìnrin rẹ̀ dúró ni òkèèrè láti wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ọmọ náà.


Amramu sì fẹ́ Jokebedi arábìnrin baba rẹ̀ ní ìyàwó. Jokebedi sì bí Aaroni àti Mose fún un. Amramu lo ẹ̀tàdínlógóje (137) ọdún láyé.


“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá arábìnrin baba rẹ lòpọ̀ nítorí pé ìbátan baba rẹ ni.


Miriamu àti Aaroni sọ̀rọ̀-òdì sí Mose nítorí pé ó fẹ́ obìnrin ará Etiopia.


Ní oṣù kìn-ín-ní, gbogbo àgbájọ ọmọ Israẹli gúnlẹ̀ sí pápá Sini, wọ́n sì dúró ní Kadeṣi. Níbẹ̀ ni Miriamu kú, wọ́n sì sin ín.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan