Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 26:4 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 “Ka iye àwọn ọkùnrin tí ó jẹ́ ọmọ-ogun (20) ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.” Èyí ni àwọn ọmọ Israẹli tí ó jáde láti Ejibiti wá:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 wọ́n sọ fún wọn pé, “Ẹ ka iye àwọn eniyan náà láti ẹni ogún ọdún lọ sókè,” gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n jáde láti ilẹ̀ Ijipti nìwọ̀nyí:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Ẹ kà iye awọn enia na, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose, ati fun awọn ọmọ Israeli, ti o ti ilẹ Egipti jade wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 26:4
6 Iomraidhean Croise  

Èyí ni orúkọ àwọn ọmọ Israẹli (Jakọbu àti Ìran rẹ̀) tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ Ejibiti: Reubeni àkọ́bí Jakọbu.


Satani sì dúró ti Israẹli, ó sì ti Dafidi láti ka iye Israẹli.


Àti pé ní ọjọ́ náà gan an ni Olúwa mú àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti gẹ́gẹ́ bí ìpín ìpín wọn.


Olúwa bá Mose sọ̀rọ̀ ní aginjù Sinai nínú àgọ́ àjọ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kejì ní ọdún kejì tí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, ó wí pé:


Lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ ti Moabu pẹ̀lú Jordani tí ó kọjá Jeriko, Mose àti Eleasari àlùfáà sọ̀rọ̀ pẹ̀lú wọn ó wí pé,


Àwọn ọmọ Reubeni, àkọ́bí ọmọkùnrin Israẹli, láti ẹni ti ìdílé Hanoku, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ìdílé Hanoku ti jáde wá; Láti ìdílé Pallu, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ìdílé àwọn ọmọ Pallu ti jáde wá;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan