Numeri 24:9 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní9 Ó tẹríba ó sì dùbúlẹ̀ bí kìnnìún, bí abo kìnnìún: ta ni ó gbọdọ̀ jí wọn? “Ìbùkún ni fún ẹni tí ó bùkún fún ọ, kí ìfibú jẹ́ ti ẹni tí ó fi ọ́ bú!” Faic an caibideilYoruba Bible9 Ó dùbúlẹ̀, ó ba bíi kinniun, bí abo kinniun tí ó sùn, ta ló lè jí i dìde? Ibukun ni fún ẹni tí ó bá súre fún Israẹli, ẹni tí ó bá sì gbé Israẹli ṣépè, olúwarẹ̀ gbé!” Faic an caibideilBibeli Mimọ9 O ba, o dubulẹ bi kiniun, ati bi abo-kiniun: tani yio lé e dide? Ibukún ni fun ẹniti o sure fun ọ, ifibú si ni ẹniti o fi ọ bú. Faic an caibideil |
Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi: “Gẹ́gẹ́ bí i kìnnìún ti í ké àní kìnnìún ńlá lórí ẹran ọdẹ rẹ̀ bí a tilẹ̀ rí ẹgbẹ́ àwọn olùṣọ́-àgùntàn tí a sì pè wọ́n papọ̀ láti kojú rẹ̀, ẹ̀rù kò lè bà á pẹ̀lú igbe wọn akitiyan wọn kò sì lè dí i lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò sọ̀kalẹ̀ wá láti jagun lórí òkè Sioni àti lórí ibi gíga rẹ̀.