Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 24:8 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 “Ọlọ́run mú wọn jáde láti Ejibiti wá; wọ́n ní agbára gẹ́gẹ́ bí i ti àgbáǹréré. Wọ́n jẹ orílẹ̀-èdè tí ń ṣe ọ̀tá rẹ̀ run, wọ́n sì fọ́ egungun wọn sí túútúú; wọ́n ó sì fi ọfà wọn ta wọ́n ní àtapòyọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 Ọlọrun kó wọn ti Ijipti wá, ó jà fún wọn gẹ́gẹ́ bí àgbáǹréré. Wọn yóo pa àwọn ọ̀tá wọn run, wọn óo wó egungun wọn, wọn óo sì fi ọfà pa wọ́n.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Ọlọrun mú u lati Egipti jade wá; o ní agbara bi ti agbanrere: on o jẹ awọn orilẹ-ède ti iṣe ọtá rẹ̀ run, yio si fọ́ egungun wọn, yio si fi ọfà rẹ̀ ta wọn li atapoyọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 24:8
18 Iomraidhean Croise  

Ìwọ yóò fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn ìwọ yóò sì rún wọn wómúwómú bí ìkòkò amọ̀.”


Nítorí pé ìwọ yóò mú wọn yí ẹ̀yìn wọn padà nígbà tí o bá pinnu láti ta wọ́n ní ọfà.


Jẹ́ kí ọfà mímú rẹ̀ dá ọkàn àwọn ọ̀tá ọba lu jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè ṣubú sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.


Ọlọ́run láé, àti láéláé ni ìtẹ́ rẹ, ọ̀pá aládé ìjọba rẹ, ọ̀pá aládé òtítọ́ ni.


Bí ìwọ bá fetísílẹ̀ dáradára sí ohùn rẹ̀ tí ẹ sì ṣe ohun gbogbo ti mo ní kí ẹ ṣe, èmi yóò jẹ́ ọ̀tá àwọn ọ̀tá yín. Èmi yóò sì fóòro àwọn tí ń fóòro yín.


Èmi fi sùúrù dúró títí di àfẹ̀mọ́júmọ́, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí kìnnìún ó ti fọ́ gbogbo egungun mi; ọ̀sán àti òru ni ìwọ fi ṣe òpin mi.


“Israẹli jẹ́ àgùntàn tí ó ṣìnà kiri, kìnnìún sì ti lé e lọ. Níṣàájú ọba Asiria pa á jẹ, àti níkẹyìn yìí Nebukadnessari ọba Babeli fa egungun rẹ̀ ya.”


Nítorí pé èmi yóò ru, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò gbé sókè sí Babeli àwọn orílẹ̀-èdè ńlá láti ilẹ̀ àríwá. Wọn yóò gba àyà wọn lẹ́gbẹ́ rẹ̀; Láti àríwá wá, à ó sì mú ọ. Ọfà wọn yóò dàbí ọfà àwọn akọni akíkanjú tí wọn kì í wà lọ́wọ́ òfo


Ọba pàṣẹ pé, kí a mú àwọn alátakò Daniẹli wá, kí a jù wọ́n sí inú ihò kìnnìún, pẹ̀lú ìyàwó àti àwọn ọmọ wọn. Kí wọn tó dé ìsàlẹ̀ ihò, kìnnìún lágbára lórí i wọn, wọ́n sì fọ́ gbogbo egungun wọn.


Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa. Kí ẹ sì má bẹ̀rù àwọn ènìyàn ìlú náà, nítorí pé a ó gbé wọn mì, ààbò wọn ti fi wọ́n sílẹ̀, Olúwa sì wà pẹ̀lú àwa, Ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn.”


wọ́n sì sọ̀rọ̀ lòdì sí Ọlọ́run àti Mose, wọ́n wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi mú wa jáde láti Ejibiti kí a ba le wá kú sí aginjù yìí? Kò sí oúnjẹ! Kò sì sí omi! Àwa sì kórìíra oúnjẹ tí kò dára yìí!”


Ọlọ́run mú wọn jáde láti Ejibiti wá, wọ́n ní agbára màlúù ẹhànnà.


Àwọn ènìyàn náà yóò dìde bí abo kìnnìún; wọ́n yóò sì gbé ara wọn sókè bí i kìnnìún òun kì yóò sì dùbúlẹ̀ títí yóò fi jẹ ohun ọdẹ títí yóò sì fi mu nínú ẹ̀jẹ̀ ohun pípa.”


ó sì wà níbẹ̀ títí tí Herodu fi kú. Èyí jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí Olúwa sọ láti ẹnu wòlíì pé: “Mo pe ọmọ mi jáde láti Ejibiti wá.”


“Èmi yóò kó àwọn ohun búburú lé wọn lórí èmi ó sì na ọfà mi tán sí wọn lára.


Èmi yóò mú ọfà mu ẹ̀jẹ̀, nígbà tí idà mi bá jẹ ẹran: ẹ̀jẹ̀ ẹni pípa àti ẹni ìgbèkùn, láti orí àwọn aṣáájú ọ̀tá.”


Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá mú ọ dé ilẹ̀ náà, tí ìwọ yóò wọ̀ lọ láti gbà, tí ìwọ yóò sì lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè kúrò níwájú rẹ: Àwọn ará Hiti, Girgaṣi, Amori, Kenaani, Peresi, Hifi àti àwọn ará Jebusi: Àwọn orílẹ̀-èdè méje tí wọ́n lágbára tí wọ́n sì pọ̀jù ọ lọ,


Àwa ti gbọ́ bí Olúwa ti mú omi Òkun Pupa gbẹ níwájú u yín nígbà tí ẹ̀yin jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, àti ohun tí ẹ̀yin ṣe sí Sihoni àti Ogu, àwọn ọba méjèèjì ti Amori ti ìlà-oòrùn Jordani, tí ẹ̀yin parun pátápátá.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan