Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 24:7 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Omi yóò sàn láti inú garawa: èso wọn yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi. “Ọba wọn yóò ga ju Agagi lọ; ìjọba wọn yóò di gbígbéga.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

7 Òjò yóo rọ̀ fún Israẹli ní àkókò rẹ̀, omi yóo jáde láti inú agbè rẹ̀; àwọn ohun ọ̀gbìn rẹ̀ yóo sì rí omi mu. Ọba wọn yóo lókìkí ju Agagi lọ, ìjọba rẹ̀ ni a óo sì gbéga.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Omi o ṣàn jade lati inu agbè rẹ̀ wá, irú rẹ̀ yio si wà ninu omi pupọ̀, ọba rẹ̀ yio si ga jù Agagi lọ, ijọba rẹ̀ li a o si gbeleke.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 24:7
29 Iomraidhean Croise  

Dafidi sì kíyèsi i pé, Olúwa ti fi ìdí òun múlẹ̀ láti jẹ ọba lórí Israẹli, àti pé, ó gbé ìjọba rẹ̀ ga nítorí Israẹli àwọn ènìyàn rẹ̀.


Solomoni sì ń ṣàkóso lórí gbogbo àwọn ìjọba láti odò Eufurate títí dé ilẹ̀ àwọn ará Filistini, àti títí dé etí ilẹ̀ Ejibiti. Àwọn orílẹ̀-èdè yìí ń mú owó òde wá, wọ́n sì ń sin Solomoni ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.


Nígbà tí Hiramu ọba Tire sì gbọ́ pé, a ti fi òróró yan Solomoni ní ọba ní ipò Dafidi baba rẹ̀, ó sì rán àwọn ikọ̀ rẹ̀ sí Solomoni, nítorí ó ti fẹ́ràn Dafidi ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo.


Dafidi sì mọ Israẹli àti pé Olúwa ti fi òun ṣe ọba lórí Israẹli àti pé ìjọba rẹ̀ ga jùlọ nítorí ti àwọn ènìyàn rẹ̀.


Jerusalẹmu ti ní àwọn ọba alágbára tí ń jẹ ọba lórí gbogbo àwọn agbègbè Eufurate, àti àwọn owó orí, owó òde àti owó ibodè sì ni wọ́n ń san fún wọn.


Lẹ́yìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, ọba Ahaswerusi dá Hamani ọmọ Hammedata, ará Agagi lọ́lá, ọba gbé e ga, ó si fún un ní àga ọlá tí ó ju ti gbogbo àwọn ọlọ́lá tókù lọ.


Ìwọ ti gbà mí lọ́wọ́ ìkọlù àwọn ènìyàn; Ìwọ ti fi mí ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè. Àwọn ènìyàn ti èmi kò mọ, yóò sì máa sìn mí,


Ẹ fi ìyìn fún Olúwa ní ẹgbẹgbẹ́; àní fún Olúwa ẹ̀yin tí ó ti orísun Israẹli wá.


Gbogbo ọba yóò tẹríba fún un àti gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sìn ín.


Èmi yóò ṣe é ni àkọ́bí mi, Ẹni gíga ju àwọn ọba ayé.


Ní ìgbẹ̀yìn ọjọ́ òkè tẹmpili Olúwa ni a ó fi ìdí rẹ̀ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olú nínú àwọn òkè, a ó sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèkéé lọ, gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì máa sàn sínú un rẹ̀.


Ní ọjọ́ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò sọ ẹ̀mí wọn nù nígbà tí ilé ìṣọ́ yóò wó lulẹ̀, odò omi yóò sàn lórí òkè gíga àti lórí àwọn òkè kékeré.


“Tẹ́tí sí èyí, ìwọ ilé e Jakọbu, ìwọ tí a ń pè pẹ̀lú orúkọ Israẹli tí o sì wá láti ẹ̀ka Juda, ìwọ tí ò ń búra ní orúkọ Olúwa tí o sì ń pe Ọlọ́run Israẹli ṣùgbọ́n kì í ṣe ní òtítọ́ àti òdodo


Ní ti ìgbòòrò Ìjọba rẹ̀ àti àlàáfíà rẹ̀ ni kì yóò ní ìpẹ̀kun. Yóò jẹ ọba lórí ìtẹ́ Dafidi àti lórí ẹ̀kún un rẹ̀ gbogbo, nípa ìfìdímúlẹ̀ àti ìgbéró rẹ̀, pẹ̀lú òtítọ́ àti òdodo láti ìgbà náà lọ àti títí láéláé. Ìtara Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú èyí ṣẹ.


Ìwọ tí o gbé lẹ́bàá odò púpọ̀, tí o sì ni ọ̀rọ̀ púpọ̀; ìgbẹ̀yìn rẹ ti dé, àní àsìkò láti ké ọ kúrò!


“Ní àsìkò àwọn ọba náà, Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba èyí tí kò le è bàjẹ́ kalẹ̀, èyí tí a kò ní fi lé ẹlòmíràn lọ́wọ́. Yóò sì run gbogbo ìjọba, yóò sì mú wọn wá sí òpin, ṣùgbọ́n ìjọba yìí yóò dúró láéláé.”


Nígbà náà ni Balaamu rí Amaleki ó sì bẹ̀rẹ̀ òwe: “Amaleki ni àkọ́kọ́ nínú àwọn orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n yóò dahoro níkẹyìn.”


Nígbà náà ni Natanaeli sọ ọ́ gbangba pé, “Rabbi, ìwọ ni ọmọ Ọlọ́run; Ìwọ ni ọba Israẹli.”


Angẹli keje sì fọn ìpè; a sì gbọ́ ohùn ńlá láti ọ̀run, wí pé, “Ìjọba ayé di ti Olúwa wá, àti tí Kristi rẹ̀; òun yóò sì jẹ ọba láé àti láéláé!”


Ọ̀kan nínú àwọn angẹli méje náà tí ó ní ìgò méje wọ̀n-ọn-nì sì wá, ó sì ba mi sọ̀rọ̀ wí pé, “Wá níhìn-ín; èmi ó sì fi ìdájọ́ àgbèrè ńlá ní tí ó jókòó lórí omi púpọ̀ han ọ:


Ó sì wí fún mi pé, “Àwọn omi tí ìwọ ti rí ni, níbi tí àgbèrè náà jókòó, àwọn ènìyàn àti ẹ̀yà àti orílẹ̀ àti onírúurú èdè ni wọ́n.


Ó sì ní lára aṣọ rẹ̀ àti ni ìtàn rẹ̀ orúkọ kan tí a kọ: ọba àwọn ọba àti olúwa àwọn olúwa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan