Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 24:18 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

18 Wọn yóò borí Edomu; yóò ṣẹ́gun Seiri ọ̀tá rẹ̀, ṣùgbọ́n Israẹli yóò dàgbà nínú agbára.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

18 Yóo ṣẹgun àwọn ọ̀tá rẹ̀ ní Edomu, yóo sì gba ilẹ̀ wọn. Yóo ṣẹgun àwọn ará Seiri tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá wọn, yóo sì gba ilẹ̀ wọn. Israẹli yóo sì máa pọ̀ sí i ní agbára.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

18 Edomu yio si di iní, Seiri pẹlu yio si di iní, fun awọn ọtá rẹ̀; Israeli yio si ṣe iṣe-agbara.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 24:18
15 Iomraidhean Croise  

kí wọn le jogún ìyókù Edomu àti gbogbo àwọn kèfèrí, ti a ń pè nípa orúkọ mi,” ni Olúwa, ẹni tí yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí wí.


Ó sì fi àwọn ológun sí Edomu; àti ní gbogbo Edomu yíká ni òun sì fi ológun sí, gbogbo àwọn tí ó wà ní Edomu sì wá sin Dafidi, Olúwa sì fún Dafidi ní ìṣẹ́gun níbikíbi tí ó ń lọ.


Kí àwọn orílẹ̀-èdè kí ó máa sìn ọ́, kí àwọn ènìyàn sì máa tẹríba fún ọ, máa ṣe olórí àwọn arákùnrin rẹ, kí àwọn iyèkan rẹ sì máa wólẹ̀ fún ọ Fífibú ni àwọn ẹni tó fi ọ́ bú, Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ó súre fún ọ.”


Ta nì eléyìí tí ó Edomu wá, ti òun ti aṣọ àrẹpọ́n láti Bosra wá? Ta nì eléyìí, tí ó ní ògo nínú aṣọ rẹ̀, tí ó ń yan bọ̀ wá nínú ọláńlá agbára rẹ̀? “Èmi ni ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ nínú òdodo tí ó ní ipa láti gbàlà.”


Nítorí ti a rẹ idà mi ní ọ̀run, kíyèsi í, yóò sọ̀kalẹ̀ wá sórí Edomu, sórí àwọn ènìyàn tí mo ti parun fún ìdájọ́.


Ìwọ ti kọ̀ wá sílẹ̀, Ọlọ́run, ìwọ ti tú wa ká, ìwọ ti bínú nísinsin yìí, tún ara rẹ yípadà sí wa.


Jakọbu sì rán àwọn oníṣẹ́ ṣáájú ara rẹ̀ sí Esau arákùnrin rẹ̀ ni ilẹ̀ Seiri ní orílẹ̀-èdè Edomu.


Nípa idà rẹ ni ìwọ yóò máa gbé, ìwọ yóò sì máa sin àbúrò rẹ, ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn, nígbà tí ìwọ bá di alágbára ìwọ yóò já àjàgà rẹ̀ kúrò lọ́rùn rẹ.”


Ṣùgbọ́n Edomu dáhùn pé: “Ẹ̀yin kò le gba ibí kọjá; bí ẹ bá dán an wò, a ó dìde ogun sí yín, a ó sì bá yín jà pẹ̀lú idà.”


Olórí yóò jáde láti Jakọbu yóò sì pa àwọn tó ṣẹ́kù nínú ìlú náà run.”


“Ní ọjọ́ náà ní Èmi yóò gbé àgọ́ Dafidi tí ó wó ró, Èmi yóò dí odi rẹ̀ tí ó ya, Èmi yóò sì gbé ahoro rẹ̀ sókè, Èmi yóò sì kọ bí ti ọjọ́ ìgbàanì,


“Kíyèsi i, Èmi yóò sọ ọ́ di kékeré láàrín àwọn kèfèrí; ìwọ yóò sì di gígàn lọ́pọ̀lọpọ̀,


Nígbà náà ni Olúwa gbé ọ̀tá kan dìde sí Solomoni, Hadadi ará Edomu ìdílé ọba ni ó ti wá ní Edomu.


Ó sì ṣe, nígbà tí Dafidi wà ní Edomu, Joabu olórí ogun sì gòkè lọ láti sin àwọn ọmọ-ogun Israẹli ti a pa lójú ogun, ó sì pa gbogbo ọkùnrin Edomu.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan