Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 24:10 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Nígbà náà ni ìbínú Balaki sì dé sí Balaamu. Ó sì fi ọwọ́ lu ọwọ́ ó wí pé, “Mo pè ọ́ láti bú àwọn ọ̀tá mi ṣùgbọ́n o tún bùkún fún wọn nígbà mẹ́ta yìí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

10 Balaki bá bínú sí Balaamu gidigidi, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi ọwọ́ lu ọwọ́. Ó sì sọ fún Balaamu pé: “Mo pè ọ́ pé kí o wá gbé àwọn ọ̀tá mi ṣépè, ṣugbọn dípò kí o gbé wọ́n ṣépè, o súre fún wọn ní ìgbà mẹta!

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 Ibinu Balaki si rú si Balaamu, o si fi ọwọ́ lù ọwọ́ pọ̀: Balaki si wi fun Balaamu pe, Emi pè ọ lati fi awọn ọtá mi bú, si kiyesi i iwọ si súre fun wọn patapata ni ìgba mẹta yi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 24:10
15 Iomraidhean Croise  

Nítorí wọn kò mú oúnjẹ àti omi wá pàdé àwọn ọmọ Israẹli lọ́nà, dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n bẹ Balaamu ní ọ̀wẹ̀ láti gégùn ún lé wọn lórí (Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa yí ègún náà padà sí ìbùkún).


Àwọn ènìyàn yóò sì ṣápẹ́ sí i lórí, wọn yóò sì ṣe síọ̀ sí i kúrò ní ipò rẹ̀.”


“Nítorí náà, ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì fi ọwọ́ lu ọwọ́ Jẹ́ kí idà lu ara wọn lẹ́ẹ̀méjì, kódà ní ẹ̀ẹ̀mẹta. Ó jẹ́ idà fún ìpànìyàn idà fún ìpànìyàn lọ́pọ̀lọpọ̀ Tí yóò sé wọn mọ́ níhìn-ín àti lọ́hùnnún.


Èmi gan an yóò pàtẹ́wọ́ ìbínú mi yóò sì rẹlẹ̀ Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀.”


“ ‘Èmi yóò kúkú pàtẹ́wọ́ lórí èrè àìmọ̀ tí ìwọ ti jẹ, àti lórí ẹ̀jẹ̀ tí ìwọ ti ta sílẹ̀ ní àárín yín.


‘Àwọn ènìyàn kan ti ilẹ̀ Ejibiti jáde wá tí wọ́n bo ojú ilẹ̀. Nísinsin yìí, wá, kí o wá fi wọ́n bú fún mi. Bóyá Èmi yóò lè bá wọn jà, èmi ó sì lé wọn jáde.’ ”


Nítorí pé èmi yóò fún ọ ní ẹ̀bùn dáradára, èmi yóò sì ṣe ohunkóhun tí ìwọ bá sọ. Wá, kí o sì wá fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí bú fún mi.”


Nísinsin yìí, wá fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí bú, nítorí wọ́n ní agbára jù fún mi. Nípa ṣíṣe èyí èmi ó ṣẹ́gun wọn, kí n sì lé wọn kúrò ní ilẹ̀ yìí. Nítorí tí mo mọ̀ pé ìbùkún ni fún àwọn tí ìwọ bá bùkún, ìfibú sì ni ẹni tí ìwọ bá fi bú.”


Balaki sọ fún Balaamu pé, “Kí lo ṣe fún mi? Mo gbé ọ wá láti fi àwọn ọ̀tá mi bú, Ṣùgbọ́n o kò ṣe nǹkan kan Ṣùgbọ́n o bùkún wọn!”


Nísinsin yìí sálọ sí ibùjókòó rẹ! Èmi ti rò láti sọ ọ́ di ẹni ńlá, ṣùgbọ́n Olúwa tí fà ọ́ sẹ́yìn láti gba èrè yìí.”


Ó tẹríba ó sì dùbúlẹ̀ bí kìnnìún, bí abo kìnnìún: ta ni ó gbọdọ̀ jí wọn? “Ìbùkún ni fún ẹni tí ó bùkún fún ọ, kí ìfibú jẹ́ ti ẹni tí ó fi ọ́ bú!”


Èyí sì ṣẹlẹ̀ nígbà mẹ́ta; a sì tún fa gbogbo rẹ̀ sókè ọ̀run.


Ìwọ kò gbọdọ̀ wá àlàáfíà, tàbí ire wọn níwọ̀n ìgbà tí o sì wà láààyè.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan