Numeri 23:7 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní7 Nígbà náà ni Balaamu sọ ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ jáde wí pé: “Balaki mú mi láti Aramu wá, Ọba Moabu láti òkè ìlà-oòrùn wá Ó wí pé, ‘Wá fi Jakọbu bú fún mi; wá, kí o sì jẹ́rìí sí Israẹli.’ Faic an caibideilYoruba Bible7 Balaamu bá bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, ó ní: “Láti Aramu, Balaki mú mi wá, ọba Moabu mú mi wá láti àwọn òkè ìlà oòrùn. Ó sọ pé, ‘Wá ba mi ṣépè lé Jakọbu, kí o sì fi Israẹli ré.’ Faic an caibideilBibeli Mimọ7 O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Balaki ọba Moabu mú mi lati Aramu wá, lati òke-nla ìla-õrún wá, wipe, Wá, fi Jakobu bú fun mi, si wá, ki o fi Israeli ré. Faic an caibideil |
Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin pẹ̀lú àwọn àgbàgbà fẹ́ mú Jesu lákokò náà. Nítorí tí wọ́n mọ̀ pé àwọn ló ń pòwe mọ́ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àwọn ni alágbàtọ́jú búburú nínú ìtàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà wọ́n láti fọwọ́ kàn án nítorí pé wọ́n bẹ̀rù ìhùwàsí ọ̀pọ̀ ènìyàn tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Nítorí náà wọ́n fi í sílẹ̀ lọ.