Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 23:19 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

19 Ọlọ́run kì í ṣe ènìyàn, tí yóò fi purọ́, tàbí ọmọ ènìyàn, tí ó lè yí ọkàn rẹ̀ padà. Ǹjẹ́ ó sọ̀rọ̀ kí ó má ṣe é? Ǹjẹ́ ó ti ṣèlérí kí ó má mu un ṣẹ?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

19 Ọlọrun kò jọ eniyan tí máa ń purọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe eniyan tí máa ń yí ọkàn pada. Ohun tí ó bá ti sọ ni yóo ṣe, bí ó bá sì sọ̀rọ̀ yóo rí bẹ́ẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

19 Ọlọrun ki iṣe enia ti yio fi ṣeké; bẹ̃ni ki iṣe ọmọ enia ti yio fi ronupiwada: a ma wi, ki o má si ṣe bi? tabi a ma sọ̀rọ ki o má mu u ṣẹ?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 23:19
36 Iomraidhean Croise  

Máa ṣe àtìpó ní ilẹ̀ yìí fún ìgbà díẹ̀, èmi ó sì wà pẹ̀lú rẹ, Èmi yóò sì bùkún fún ọ. Nítorí ìwọ àti irú-ọmọ rẹ ni èmi yóò fi gbogbo àwọn ilẹ̀ wọ̀nyí fún, èmi yóò sì fi ìdí ìbúra tí mo ṣe fún Abrahamu baba rẹ múlẹ̀.


Èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì pa ọ mọ́ ní ibikíbi tí ìwọ bá lọ, èmi yóò sì mú ọ padà wá sí ilẹ̀ yìí ní àlàáfíà. Èmi kì yóò fi ọ sílẹ̀ ní ìgbà kan, títí tí èmi yóò fi mú gbogbo ìlérí mi ṣẹ.”


Ajá yóò jẹ ẹni Jeroboamu tí ó bá kú ní ìlú, àti ẹni tí ó bá kú ní igbó ni àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run yóò jẹ. Olúwa ti sọ ọ́!’


Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí a sọ fún Jehu jẹ́ ìmúṣẹ: “Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò jókòó lórí ìtẹ́ Israẹli títí dé ìran kẹrin.”


Ìjòyè kan ẹni tí ọwọ́ ọba ń fi ara tì dáhùn wí fún ènìyàn Ọlọ́run pé, “Ẹ wò ó, tí Olúwa bá tilẹ̀ ṣí fèrèsé ọ̀run sílẹ̀, ṣé èyí lè rí bẹ́ẹ̀?” “Ìwọ yóò rí i pẹ̀lú ojú rẹ,” Eliṣa dáhùn, “ṣùgbọ́n ìwọ kò ní jẹ nǹkan kan lára rẹ̀!”


Pẹ̀lú bí ẹni pé èyí kò tó lójú rẹ, Ọlọ́run. Ìwọ ti sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ iwájú ilé ìránṣẹ́ rẹ. Ìwọ ti wò mí bí ẹni pé èmi ni ẹni gbígbéga jù láàrín àwọn ọkùnrin Olúwa Ọlọ́run.


Olúwa ti búra, kò sì í yí ọkàn padà pé, “Ìwọ ni àlùfáà, ní ipasẹ̀ Melkisedeki.”


Olúwa ti búra nítòótọ́ fún Dafidi: Òun kì yóò yípadà kúrò nínú rẹ̀, nínú irú-ọmọ inú rẹ ni èmi ó gbé kalẹ̀ sí orí ìtẹ́ rẹ.


Ọlọ́run ha gbàgbé láti máa ṣàánú? Ní ìbínú rẹ̀, ó ha sé ojúrere rẹ̀ mọ́?” Sela.


Èmi kì yóò sẹ́ májẹ̀mú mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò yí ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu mi jáde padà.


Lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo ni èmi ti fi ìwà mímọ́ mi búra; èmi kì yóò purọ́ fún Dafidi.


Àwọn tafàtafà tí ó sálà, àwọn jagunjagun Kedari kò ní tó nǹkan.” Olúwa, Ọlọ́run Israẹli ni ó ti sọ̀rọ̀.


Síbẹ̀síbẹ̀ òun pẹ̀lú jẹ́ ọlọ́gbọ́n ó sì lè mú ìparun wá; òun kì í kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ. Òun yóò dìde sí ilé àwọn ìkà, àti sí àwọn tí ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún aṣebi.


Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa dúró títí láé.”


Láti ìlà-oòrùn wá ni mo ti pe ẹyẹ ajẹran wá; láti ọ̀nà jíjìn réré, ọkùnrin kan tí yóò mú ète mi ṣẹ. Ohun tí mo ti sọ, òun ni èmi yóò mú ṣẹ; èyí tí mo ti gbèrò, òun ni èmi yóò ṣe.


bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tí ó jáde láti ẹnu mi wá; kì yóò padà sọ́dọ̀ mi lọ́wọ́ òfo, ṣùgbọ́n yóò ṣe ohun tí mo fẹ́, yóò sì mú ète mi tí mo fi rán an wá sí ìmúṣẹ.


Nítorí náà, ayé yóò pohùnréré ẹkún àwọn ọ̀run lókè yóò ṣú òòkùn nítorí mo ti sọ, mo sì ti pète rẹ̀ mo ti pinnu, n kì yóò sì yí i padà.”


Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ sí Nebukadnessari ọba.


Èmi kò ni mú ìbínú gbígbóná mi ṣẹ, tàbí kí èmi wá sọ Efraimu di ahoro. Nítorí pé èmi ni Ọlọ́run, àní, èmi kì í ṣe ènìyàn Ẹni mímọ́ láàrín yín, Èmi kò ní í wá nínú ìbínú


Ìwọ yóò fi òtítọ́ hàn sí Jakọbu ìwọ yóò sì fi àánú hàn sí Abrahamu, bí ìwọ ṣe búra fún àwọn baba wa láti ọjọ́ ìgbàanì.


Nítorí ìṣípayá náà jẹ́ tí ìgbà kan tí a múra sílẹ̀ dè; yóò máa yára sí ìgbẹ̀yìn kí yóò sìsọ èké. Bí o tilẹ̀ lọ́ra, dúró dè é; nítorí, dájúdájú, yóò dé, kí yóò sí pẹ́.”


“Èmi Olúwa kò yípadà. Nítorí náà ni a kò ṣe run ẹ̀yin ọmọ Jakọbu.


Èmi, Olúwa, lo sọ bẹ́ẹ̀; Èmi ó sì ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí sí ìjọ ènìyàn búburú yìí tí wọ́n kó ra wọn jọ lòdì sí mi. Nínú aginjù yìí ni òpin yóò dé bá wọn, ibẹ̀ ni wọn yóò kú sí.”


Nígbà náà ó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ sísọ: “Dìde, Balaki; kí o sì gbọ́ mi ọmọ Sippori.


Ọ̀run àti ayé yóò rékọjá: ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi kì yóò rékọjá.


Nítorí àìlábámọ̀ ni ẹ̀bùn àti ìpè Ọlọ́run.


Ṣùgbọ́n kì í ṣe pé nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di asán. Kì í sá í ṣe gbogbo àwọn tí ó ti inú Israẹli wá, àwọn ni Israẹli:


Bí àwa kò bá gbàgbọ́, òun dúró ni olóòtítọ́: Nítorí òun kò lè sẹ́ ara rẹ̀.


ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀ tí ó dúró lórí ìrètí iyè àìnípẹ̀kun, èyí tí Ọlọ́run tí kì í purọ́ ti ṣe ìlérí rẹ̀ ṣáájú kí ayé tó bẹ̀rẹ̀,


Pé, nípa ohun àìlèyípadà méjì, nínú èyí tí kò le ṣe é ṣe fún Ọlọ́run láti ṣèké, kí a lè mú àwa tí ó ti sá sábẹ́ ààbò rẹ̀ ní ọkàn lè láti di ìrètí tí a gbé kalẹ̀ níwájú wa mú ṣinṣin:


ṣùgbọ́n ti òun jẹ́ pẹ̀lú ìbúra nígbà tí Ọlọ́run wí fún un pé, “Olúwa búra, kí yóò sì yí padà: ‘Ìwọ ni àlùfáà kan títí láé ni ipasẹ̀ ti Mekisédékì.’ ”


Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ẹ̀bùn pípé láti òkè ni ó ti wá, ó sì sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ baba ìmọ́lẹ̀ wá, lọ́dọ̀ ẹni tí kò lè yípadà gẹ́gẹ́ bí òjìji àyídà.


Ẹ̀yin ṣe bí Ìwé mímọ́ sọ lásán pé, Ẹ̀mí tí ó fi sínú wa ń jowú gidigidi lórí wa?


Kò sí ọ̀kan nínú ìlérí rere tí Olúwa ṣe fún ilé Israẹli tí ó kùnà; Gbogbo rẹ̀ ni ó ṣe.


Ẹni tí ó ń ṣe ògo Israẹli, kì í purọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì í yí ọkàn rẹ̀ padà; nítorí kì í ṣe ènìyàn tí yóò yí ọkàn rẹ̀ padà.”


Ní ìgbà náà ni èmi yóò mú ohun gbogbo tí mo ti sọ sí ilé Eli ṣẹ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan