Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 23:13 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

13 Nígbà náà Balaki sọ fún un pé, “Wá pẹ̀lú mi sí ibòmíràn tí o ti lè rí wọn; wà á rí díẹ̀ Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo wọn. Láti ibẹ̀, wá fi wọ́n bú fún mi.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

13 Balaki sọ fún Balaamu pé, “Jẹ́ kí á lọ sí ibòmíràn tí o ti lè rí wọn. Apákan wọn ni o óo rí, o kò ní rí gbogbo wọn, níbẹ̀ ni o óo ti bá mi ṣépè lé wọn.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

13 Balaki si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, bá mi lọ si ibomiran, lati ibiti iwọ o le ri wọn; kìki apakan wọn ni iwọ o ri, iwọ ki yio si ri gbogbo wọn tán; ki o si fi wọn bú fun mi lati ibẹ̀ lọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 23:13
10 Iomraidhean Croise  

Àwọn ìránṣẹ́ ọba Aramu sì wí fún un pé, “Ọlọ́run wọn, ọlọ́run òkè ni. Ìdí nìyìí tí wọ́n ṣe ní agbára jù wá lọ. Ṣùgbọ́n bí a bá bá wọn jà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, àwa yóò ní agbára jù wọ́n lọ dájúdájú.


Ènìyàn Ọlọ́run kan sì gòkè wá, ó sì sọ fún ọba Israẹli pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Nítorí tí àwọn ará Aramu rò pé Olúwa, Ọlọ́run òkè ni, ṣùgbọ́n òun kì í ṣe Ọlọ́run Àfonífojì, nítorí náà èmi ó fi gbogbo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn yìí lé ọ lọ́wọ́, ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.’ ”


Ó fẹ́ràn láti máa mú ègún wá sí orí rẹ̀: bi inú rẹ̀ kò ti dùn si ìre, bẹ́ẹ̀ ni kí ó jìnnà sí.


Ìwọ ènìyàn mi, rántí ohun tí Balaki ọba Moabu gbèrò àti ohun tí Balaamu ọmọ Beori dáhùn. Rántí ìrìnàjò rẹ̀ láti Ṣittimu dé Gilgali, kí ìwọ ba le mọ òdodo Olúwa.”


Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì Balaki gbé Balaamu lọ sí Bamoti Baali, láti ibẹ̀ ló ti rí apá kan àwọn ènìyàn.


Nísinsin yìí, wá fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí bú, nítorí wọ́n ní agbára jù fún mi. Nípa ṣíṣe èyí èmi ó ṣẹ́gun wọn, kí n sì lé wọn kúrò ní ilẹ̀ yìí. Nítorí tí mo mọ̀ pé ìbùkún ni fún àwọn tí ìwọ bá bùkún, ìfibú sì ni ẹni tí ìwọ bá fi bú.”


Ó sì dáhùn wí pé, “Ṣé kí n má sọ nǹkan tí Olúwa fi sí mi lẹ́nu?”


Ó sì lọ sí pápá Ṣofimu ní orí òkè Pisga, ó sì kọ́ pẹpẹ méje síbẹ̀ ó sì fi akọ màlúù àti àgbò kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.


Nígbà tí Balaki ọmọ Sippori, ọba Moabu, múra láti bá Israẹli jà, ó ránṣẹ́ sí Balaamu ọmọ Beori láti fi yín bú.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan