Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 23:12 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Ó sì dáhùn wí pé, “Ṣé kí n má sọ nǹkan tí Olúwa fi sí mi lẹ́nu?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

12 Ó sì dáhùn pé, “Ohun tí OLUWA bá sọ fún mi ni mo gbọdọ̀ sọ.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 On si dahùn o si wipe, Emi ha le ṣe aiṣọra lati sọ eyiti OLUWA fi si mi li ẹnu bi?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 23:12
11 Iomraidhean Croise  

Ìwọ yóò sọ̀rọ̀ fún un, ìwọ yóò sì fi ọ̀rọ̀ sí i lẹ́nu: Èmi yóò ràn yín lọ́wọ́ láti sọ̀rọ̀. Èmi yóò kọ́ ọ yín ni ohun ti ẹ ó ṣe.


Bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tilẹ̀ fanimọ́ra, má ṣe gbà á gbọ́ nítorí ìríra méje ni ó kún inú ọkàn rẹ̀.


Ní alẹ́ ọjọ́ náà Ọlọ́run sì tọ Balaamu wá ó sì sọ wí pé, “Nígbà tí ọkùnrin yìí ti wá pè ọ́, lọ pẹ̀lú wọn, ṣùgbọ́n ẹnu nǹkan tí mo sọ fún ọ ni kí o ṣe.”


Balaamu sì wí fún Balaki pé “Kíyèsi, èmi tọ̀ ọ́ wá, èmi kò ha ní agbára kan nísinsin yìí rárá láti wí ohun kan? Mo gbọdọ̀ sọ nǹkan tí Ọlọ́run fi sí mi lẹ́nu.”


Nígbà náà Balaki sọ fún un pé, “Wá pẹ̀lú mi sí ibòmíràn tí o ti lè rí wọn; wà á rí díẹ̀ Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo wọn. Láti ibẹ̀, wá fi wọ́n bú fún mi.”


Èmi gba àṣẹ láti bùkún; Ó sì ti bùkún, èmi kò sì lè yípadà.


Balaamu dáhùn ó sì wí fún Balaki pé, “Ǹjẹ́ èmi kò ha ti wí fún ọ pé, gbogbo èyí tí Olúwa bá sọ, òun ni èmi yóò ṣe?”


Nígbà náà Balaamu sọ fún Balaki pé, “Dúró ti ẹbọ sísun rẹ kí èmi sì lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan. Bóyá Olúwa yóò farahàn mí. Ohunkóhun tí ó bá fihàn mí, èmi yóò wí fún ọ.” Nígbà náà ó sì lọ sí ibi gíga.


‘Kódà bí Balaki bá fún mi ní ààfin rẹ̀ tí ó kún fún fàdákà àti wúrà, èmi kò le ṣe ohunkóhun lọ́wọ́ ara mi, yálà búburú tàbí rere, láti kọjá òfin Olúwa: ohun tí Olúwa bá wí ni èmi ó sọ’?


Nítorí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò sin Kristi Olúwa wa, bí kò ṣe ikùn ara wọn. Nípa ọ̀rọ̀ rere àti ọ̀rọ̀ dídùndídùn ni wọ́n fi ń yí àwọn aláìmọ̀kan ní ọkàn padà.


Wọ́n ń fẹnu sọ wí pé àwọn mọ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n wọ́n sẹ́ ẹ nípa ìṣe wọn. Wọ́n díbàjẹ́, wọn si jẹ aláìgbọ́ràn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kò wúlò lọ́nàkọnà ní ti iṣẹ́ rere gbogbo.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan