Numeri 22:6 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní6 Nísinsin yìí, wá fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí bú, nítorí wọ́n ní agbára jù fún mi. Nípa ṣíṣe èyí èmi ó ṣẹ́gun wọn, kí n sì lé wọn kúrò ní ilẹ̀ yìí. Nítorí tí mo mọ̀ pé ìbùkún ni fún àwọn tí ìwọ bá bùkún, ìfibú sì ni ẹni tí ìwọ bá fi bú.” Faic an caibideilYoruba Bible6 Agbára wọn ju tèmi lọ, nítorí náà, wá bá mi ṣépè lé wọn, bóyá bí mo bá bá wọn jagun, n óo lè ṣẹgun wọn, kí n sì lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ mi. Mo mọ̀ dájú pé ibukun ni fún ẹni tí o bá súre fún; ẹni tí o bá ṣépè fún, olúwarẹ̀ gbé!” Faic an caibideilBibeli Mimọ6 Njẹ nisisiyi wa, emi bẹ̀ ọ, fi awọn enia yi bú fun mi; nitoriti nwọn lí agbara jù fun mi; bọya emi o bori, ki awa ki o kọlù wọn, ki emi ki o le lé wọn lọ kuro ni ilẹ yi: nitoriti emi mọ̀ pe ibukún ni fun ẹniti iwọ ba bukún, ifibú si ni ẹniti iwọ ba fibú. Faic an caibideil |