Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 22:4 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Moabu sọ fún àwọn àgbàgbà Midiani pé, “Nísinsin yìí ni àwọn wọ̀nyí yóò lá gbogbo ohun tí ó yí wa ká, bí màlúù ṣe ń jẹ koríko tí ó wà nínú oko.” Bẹ́ẹ̀ ni Balaki ọmọ Sippori, tí ó jẹ́ ọba Moabu nígbà náà,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 Àwọn ará Moabu ranṣẹ sí àwọn olórí Midiani pé, “Àwọn eniyan wọnyi yóo run gbogbo ohun tí ó wà ní àyíká wa bí ìgbà tí mààlúù bá jẹ koríko ninu pápá.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Moabu si wi fun awọn àgba Midiani pe, Nisisiyi li awọn ẹgbẹ yi yio lá ohun gbogbo ti o yi wa ká, bi akọmalu ti ilá koriko igbẹ́. Balaki ọmọ Sippori si jẹ́ ọba awọn ara Moabu ni ìgba na.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 22:4
13 Iomraidhean Croise  

Wọ́n sì dìde kúrò ní Midiani, wọ́n sì lọ sí Parani. Nígbà náà ni wọ́n mú ènìyàn pẹ̀lú wọn láti Parani wá, wọ́n sì lọ sí Ejibiti, sọ́dọ̀ Farao ọba Ejibiti ẹni tí ó fún Hadadi ní ilé àti ilẹ̀, ó sì fún un ní oúnjẹ.


Ìbẹ̀rù yóò mú àwọn ìjòyè Edomu, Àwọn olórí Moabu yóò wárìrì Àwọn ènìyàn Kenaani yóò sì yọ́ dànù;


Ẹkún ńlá ní yóò wà lórí gbogbo òrùlé Moabu, àti ní ìta rẹ̀, nítorí èmi ti fọ́ Moabu bí a ti ń fọ́ ohun èlò tí kò wu ni,” ni Olúwa wí.


Nísinsin yìí, Balaki ọmọ Sippori rí gbogbo ohun tí àwọn Israẹli ti ṣe sí àwọn ará Amori,


Àti àwọn àgbàgbà Moabu àti Midiani sì lọ pẹ̀lú owó àyẹ̀wò lọ́nà wọn, Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Balaamu, wọ́n sọ nǹkan tí Balaki sọ fún wọn.


“Mo rí i, ṣùgbọ́n kì í ṣe ìsinsin yìí, Mo kíyèsi, ṣùgbọ́n kò súnmọ́. Ìràwọ̀ kan yóò jáde láti ọ̀dọ̀ Jakọbu; yóò yọ jáde láti Israẹli. Yóò tẹ̀ fọ́ orí Moabu, yóò sì fọ́ agbárí gbogbo ọmọ Seti.


Nítòótọ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin Israẹli sì mú obìnrin Midiani wá síwájú ojú Mose àti gbogbo ìjọ ti Israẹli wọ́n sì ń sọkún ní àbáwọlé àgọ́ ìpàdé.


Olúwa sọ fún Mose pé,


Wọ́n sì pa àwọn ọba Midiani pẹ̀lú: àwọn ìyókù tí wọ́n pa lára wọn ni Efi, Rekemu, Suri àti Huri, àti Reba: ọba Midiani márùn-ún, wọ́n sì fi idà pa Balaamu ọmọ Beori.


Ǹjẹ́ ìwọ ha sàn ju Balaki ọmọ Sippori, ọba Moabu lọ? Ǹjẹ́ òun ha ṣe gbólóhùn asọ̀ pẹ̀lú Israẹli bí? Tàbí òun dojú ìjà kọ wọ́n rí bí?


Àwọn ọmọ Israẹli sì túnṣe ohun tí ó burú ní ojú Olúwa, Ó sì fi wọ́n lé àwọn ará Midiani lọ́wọ́ fún ọdún méje.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan