Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 22:11 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 ‘Àwọn ènìyàn kan ti ilẹ̀ Ejibiti jáde wá tí wọ́n bo ojú ilẹ̀. Nísinsin yìí, wá, kí o wá fi wọ́n bú fún mi. Bóyá Èmi yóò lè bá wọn jà, èmi ó sì lé wọn jáde.’ ”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

11 àwọn eniyan kan, tí wọ́n wá láti Ijipti, tẹ̀dó sórí gbogbo ilẹ̀ òun. Ó fẹ́ kí n wá bá òun ṣépè lé wọn, kí ó lè bá wọn jà, kí ó sì lè lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ rẹ̀.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

11 Kiyesi i, awọn enia kan ti ilẹ Egipti jade wá, ti o bò oju ilẹ: wá nisisiyi, fi wọn bú fun mi; bọya emi o le bá wọn jà, emi a si lé wọn lọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 22:11
8 Iomraidhean Croise  

Kí àwọn orílẹ̀-èdè kí ó máa sìn ọ́, kí àwọn ènìyàn sì máa tẹríba fún ọ, máa ṣe olórí àwọn arákùnrin rẹ, kí àwọn iyèkan rẹ sì máa wólẹ̀ fún ọ Fífibú ni àwọn ẹni tó fi ọ́ bú, Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ó súre fún ọ.”


Balaamu sọ fún Ọlọ́run pé, “Balaki ọmọ Sippori, ọba Moabu, rán iṣẹ́ yìí sí mi pé:


Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún Balaamu pé, “Má ṣe bá wọn lọ. Ìwọ kò gbọdọ̀ gé ègún lé àwọn ènìyàn náà lórí, nítorí a ti bùkún wọn.”


Balaki sọ fún Balaamu pé, “Kí lo ṣe fún mi? Mo gbé ọ wá láti fi àwọn ọ̀tá mi bú, Ṣùgbọ́n o kò ṣe nǹkan kan Ṣùgbọ́n o bùkún wọn!”


Nígbà náà ni Balaamu sọ ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ jáde wí pé: “Balaki mú mi láti Aramu wá, Ọba Moabu láti òkè ìlà-oòrùn wá Ó wí pé, ‘Wá fi Jakọbu bú fún mi; wá, kí o sì jẹ́rìí sí Israẹli.’


Nígbà náà ni ìbínú Balaki sì dé sí Balaamu. Ó sì fi ọwọ́ lu ọwọ́ ó wí pé, “Mo pè ọ́ láti bú àwọn ọ̀tá mi ṣùgbọ́n o tún bùkún fún wọn nígbà mẹ́ta yìí.


Ṣùgbọ́n èmi kò fetí sí Balaamu, bẹ́ẹ̀ ni ó súre fún un yín síwájú àti síwájú sí i, mo sì gbà yín kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.


Ó sì wí fún Dafidi pé, “Ṣé ajá ni mí ni? Tí o fi tọ̀ mí wá pẹ̀lú ọ̀pá?” Filistini sì fi Dafidi bú pẹ̀lú Ọlọ́run rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan