Numeri 21:5 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní5 wọ́n sì sọ̀rọ̀ lòdì sí Ọlọ́run àti Mose, wọ́n wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi mú wa jáde láti Ejibiti kí a ba le wá kú sí aginjù yìí? Kò sí oúnjẹ! Kò sì sí omi! Àwa sì kórìíra oúnjẹ tí kò dára yìí!” Faic an caibideilYoruba Bible5 wọ́n sì sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọrun ati Mose, wọ́n ní, “Kí ló dé tí ẹ fi kó wa wá láti Ijipti, pé kí á wá kú ninu aṣálẹ̀ yìí? Kò sí oúnjẹ, kò sí omi, burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ yìí ti sú wa.” Faic an caibideilBibeli Mimọ5 Awọn enia na si bá Ọlọrun, ati Mose sọ̀ pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mú wa gòke lati Egipti jade wá lati kú li aginjù? nitoripe àkara kò sí, bẹ̃ni kò sí omi; onjẹ futẹfutẹ yi si sú ọkàn wa. Faic an caibideil |
“ ‘Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ náà ṣọ̀tẹ̀ sí mi. Wọn kò tẹ̀lé àṣẹ mi, wọn kò sì pa òfin mi mọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó bá tẹ̀lé àwọn òfin yìí, yóò yè nínú rẹ̀, wọ́n sì tún sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́. Nítorí náà, mo sọ pé èmi yóò tú ìbínú mi lórí wọn, Èmi yóò sì mú kí ìbínú gbígbóná mi wá sórí wọn ni aginjù.