Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 21:26 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

26 Heṣboni ni ìlú Sihoni ọba àwọn ará Amori, ẹni tí ó bá ọba Moabu ti tẹ́lẹ̀ jà tí ó sì gba gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀ títí dé Arnoni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

26 Heṣiboni ni olú ìlú Sihoni, ọba àwọn ará Amori. Ọba yìí ni ó bá ọba Moabu jà, ó sì gba ilẹ̀ rẹ̀ títí dé odò Arinoni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

26 Nitoripe Heṣboni ni ilunla Sihoni ọba awọn ọmọ Amori, ẹniti o ti bá ọba Moabu atijọ jà, ti o si gbà gbogbo ilẹ rẹ̀ li ọwọ́ rẹ̀, titi dé Arnoni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 21:26
13 Iomraidhean Croise  

Ọrùn rẹ rí bí ilé ìṣọ́ eyín erin. Ojú rẹ rí bí adágún ní Heṣboni ní ẹ̀bá ẹnu ibodè Bati-Rabbimu. Imú rẹ rí bí ilé ìṣọ́ Lebanoni tí ó kọ ojú sí Damasku.


Bí òkè Karmeli ṣe ṣe adé yí àwọn òkè ká Bẹ́ẹ̀ ni irun orí rẹ ṣe adé yí orí rẹ ká a fi àìdi irun rẹ mú ọba ní ìgbèkùn.


Moabu kò ní ní ìyìn mọ́, ní Heṣboni ni wọn ó pète ìparun rẹ̀, ‘Wá, kí a pa orílẹ̀-èdè náà run.’ Àti ẹ̀yin òmùgọ̀ ọkùnrin pàápàá ni a ó pa lẹ́nu mọ́, a ó fi idà lé e yín.


Ojú ti Moabu nítorí tí a wó o lulẹ̀. Ẹ hu, kí ẹ sì kígbe! Ẹ kéde rẹ̀ ní Arnoni pé, a pa Moabu run.


“Ní abẹ́ òjìji Heṣboni àwọn tí ó sá dúró láìní agbára, nítorí iná ti jáde wá láti Heṣboni, àti ọwọ́ iná láti àárín Sihoni, yóò sì jó iwájú orí Moabu run, àti agbárí àwọn ọmọ aláriwo.


Israẹli sì gba gbogbo ìlú Amori wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ pẹ̀lú Heṣboni, àti gbogbo ibùgbé ìlú tó yí i ká.


Ìdí nìyìí tí akọrin sọ wí pé: “Wá sí Heṣboni kí ẹ jẹ́ kí a tún un kọ́; jẹ́ kí ìlú Sihoni padà bọ̀ sípò.


Èyí ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣẹ́gun Sihoni ọba àwọn Amori, tí ó jẹ ọba ní Heṣboni, àti Ogu ọba Baṣani ni ó ṣẹ́gun ní Edrei, ẹni tí ó jẹ ọba ní Aṣtarotu.


Láti agbègbè Aroeri ní etí Arnoni Jọ́ọ́jì àti láti ìlú tí ń bẹ láàrín Jọ́ọ́jì, àti gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ìkọjá Medeba


sí Heṣboni àti gbogbo ìlú rẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú Diboni, Bamoti Baali, Beti-Baali-Mioni,


Agbègbè ìlú Jaseri, gbogbo ìlú Gileadi àti ìdajì orílẹ̀-èdè àwọn ọmọ ará Ammoni títí dé Aroeri, ní ẹ̀bá Rabba;


Heṣboni àti Jaseri, e pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́rin.


Fún ọ̀ọ́dúnrún ọdún (300) ni Israẹli fi ṣe àtìpó ní Heṣboni, Aroeri àti àwọn ìgbèríko àti àwọn ìlú tí ó yí Arnoni ká. Èéṣe tí ìwọ kò fi gbà wọ́n padà ní àsìkò náà?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan