Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 21:25 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

25 Israẹli sì gba gbogbo ìlú Amori wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ pẹ̀lú Heṣboni, àti gbogbo ibùgbé ìlú tó yí i ká.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

25 Àwọn ọmọ Israẹli gba gbogbo ìlú àwọn ará Amori, Heṣiboni ati àwọn ìlú tí ó wà ní agbègbè rẹ̀, wọ́n sì ń gbé inú wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

25 Israeli si gbà gbogbo ilunla wọnni: Israeli si joko ninu gbogbo ilunla ti awọn ọmọ Amori, ni Heṣboni, ati ni ilu rẹ̀ gbogbo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 21:25
17 Iomraidhean Croise  

Ọrùn rẹ rí bí ilé ìṣọ́ eyín erin. Ojú rẹ rí bí adágún ní Heṣboni ní ẹ̀bá ẹnu ibodè Bati-Rabbimu. Imú rẹ rí bí ilé ìṣọ́ Lebanoni tí ó kọ ojú sí Damasku.


Heṣboni àti Eleale ké sóde, ohùn wọn ni a gbọ́ títí fi dé Jahasi. Nítorí náà ni àwọn ọmọ-ogun Moabu ṣe kígbe tí ọkàn wọn sì rẹ̀wẹ̀sì.


Moabu kò ní ní ìyìn mọ́, ní Heṣboni ni wọn ó pète ìparun rẹ̀, ‘Wá, kí a pa orílẹ̀-èdè náà run.’ Àti ẹ̀yin òmùgọ̀ ọkùnrin pàápàá ni a ó pa lẹ́nu mọ́, a ó fi idà lé e yín.


“Ohùn igbe wọn gòkè láti Heṣboni dé Eleale àti Jahasi, láti Soari títí dé Horonaimu àti Eglati-Ṣeliṣi, nítorí àwọn omi Nimrimu pẹ̀lú yóò gbẹ


“Ní abẹ́ òjìji Heṣboni àwọn tí ó sá dúró láìní agbára, nítorí iná ti jáde wá láti Heṣboni, àti ọwọ́ iná láti àárín Sihoni, yóò sì jó iwájú orí Moabu run, àti agbárí àwọn ọmọ aláriwo.


Ẹ̀gbọ́n rẹ obìnrin ni Samaria, òun àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ n gbé ni apá àríwá rẹ, àti àbúrò rẹ obìnrin ní ń gbé ọwọ́ òsì rẹ̀: àti àbúrò rẹ obìnrin ti ń gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni Sodomu àti àwọn ọmọ rẹ obìnrin.


“ ‘Wò ó, ẹ̀ṣẹ̀ tí Sodomu ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin ṣẹ̀ nìyìí: Òun àti àwọn ọmọbìnrin rẹ gbéraga, wọ́n jẹ́ alájẹjù àti aláìbìkítà; wọn kò ran tálákà àti aláìní lọ́wọ́


“ ‘Bi o tilẹ̀ jẹ pe: èmi yóò mú ìgbèkùn wọn padà, ìgbèkùn Sodomu àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin, pẹ̀lú Samaria àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin, nígbà náà ni èmi yóò tún mú ìgbèkùn àwọn òǹdè rẹ wá láàrín wọn,


Èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá, mo sì sìn yín la aginjù já ní ogójì ọdún láti fi ilẹ̀ àwọn ará Amori fún un yín.


Heṣboni ni ìlú Sihoni ọba àwọn ará Amori, ẹni tí ó bá ọba Moabu ti tẹ́lẹ̀ jà tí ó sì gba gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀ títí dé Arnoni.


Nígbà náà ni àwọn ọmọ Israẹli sì ń gbé ní ilẹ̀ Amori.


“Atarotu, Diboni, Jaseri, Nimra, Heṣboni, Eleale, Sebamu, Nebo, àti Beoni.


Àwọn ará Hori gbé ní Seiri kí àwọn ọmọ Esau tó lé wọn kúrò níwájú wọn, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn, (wọ́n tẹ̀dó sí ààyè wọn) gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Israẹli tí ṣe ní ilẹ̀ tí Olúwa yóò fún wọn ní ìní wọn.


“ ‘Èmi mú yín wá sí ilẹ̀ àwọn ará Amori tí ó ń gbé ìlà-oòrùn Jordani. Wọ́n bá yín jà, Ṣùgbọ́n mo fi wọ́n lé yín lọ́wọ́. Èmí pa wọ́n run kúrò níwájú u yín, ẹ sì gba ilẹ̀ ẹ wọn.


Fún ọ̀ọ́dúnrún ọdún (300) ni Israẹli fi ṣe àtìpó ní Heṣboni, Aroeri àti àwọn ìgbèríko àti àwọn ìlú tí ó yí Arnoni ká. Èéṣe tí ìwọ kò fi gbà wọ́n padà ní àsìkò náà?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan