Numeri 21:22 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní22 “Jẹ́ kí a kọjá ní orílẹ̀-èdè rẹ. A kò ní kọjá sí inú oko pápá tàbí ọgbà àjàrà àbí mu omi láti inú kànga. A máa gba òpópónà náà ti ọba títí tí a ó fi la ilẹ̀ rẹ kọjá.” Faic an caibideilYoruba Bible22 “Jọ̀wọ́, gbà wá láàyè láti gba orí ilẹ̀ rẹ kọjá. Àwa ati àwọn ẹran ọ̀sìn wa kò ní yà kúrò ní ojú ọ̀nà wọ inú oko yín, tabi ọgbà àjàrà yín. Bẹ́ẹ̀ ni a kò ní mu omi kànga yín. Ojú ọ̀nà ọba ni a óo máa rìn títí a óo fi la ilẹ̀ rẹ kọjá.” Faic an caibideilBibeli Mimọ22 Jẹ ki emi là ilẹ rẹ kọja lọ: awa ki yio yà sinu oko, tabi ọgba-àjara; awa ki yio mu ninu omi kanga: ọ̀na opópo ọba li a o gbà, titi awa o fi kọja ipinlẹ rẹ. Faic an caibideil |