Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 21:18 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

18 nípa kànga tí àwọn ọmọ-aládé gbẹ́, nítorí àwọn ọlọ́lá ènìyàn ni ó gbẹ́ ẹ; tí àwọn ọlọ́lá àwọn ènìyàn sì fi ọ̀pá aládé àti ọ̀pá oyè wọn gbẹ́.” Nígbà náà wọ́n kúrò láti aginjù lọ sí Mattana,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

18 Kànga tí àwọn ọmọ aládé gbẹ́, tí àwọn olórí wà pẹlu ọ̀pá àṣẹ ọba ati ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀ wọn.” Wọ́n sì ṣí kúrò níbẹ̀ lọ sí aṣálẹ̀ Matana.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

18 Kanga na, ti awọn olori wà, ti awọn ọlọlá awọn enia si fi ọpá-alade na, ati ọpá wọn wà. Ati lati aginjù na, nwọn lọ si Mattana.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 21:18
12 Iomraidhean Croise  

Eliaṣibu olórí àlùfáà àti àwọn àlùfáà arákùnrin rẹ̀ lọ ṣiṣẹ́, wọ́n sì tún Ibodè Àgùntàn mọ. Wọ́n yà á sí mímọ́, wọ́n sì gbé ìlẹ̀kùn dúró sí ibi tí ó yẹ, wọ́n mọ ọ́n títí dé Ilé Ìṣọ́ Ọgọ́rùn-ún, èyí tí wọ́n yà sí mímọ́ títí dé ilé ìṣọ́ gíga Hananeli


Èyí tí ó tún wà ní ẹ̀gbẹ́ wọn ni àwọn ọkùnrin Tekoa tún mọ, ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́lá kò ṣe àtìlẹ́yìn fún iṣẹ́ náà lábẹ́ àwọn olórí wọn.


Nítorí Olúwa ni onídàájọ́ wa, Olúwa ni onídàájọ́ wa, Olúwa òun ni ọba wa; òun ni ẹni tí yóò gbà wá là.


Nígbà náà ni Israẹli kọ orin yìí pé: “Sun jáde, ìwọ kànga! Ẹ máa kọrin nípa rẹ̀,


láti Mattana lọ sí Nahalieli, láti Nahalieli lọ sí Bamoti,


Nítorí pé nípasẹ̀ Mose ni a ti fi òfin fún ni ṣùgbọ́n òun; oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́ láti ipasẹ̀ Jesu Kristi wá.


òfin tí Mose fi fún wa, ìní ti ìjọ ènìyàn Jakọbu.


Ṣùgbọ́n ìwọ túbọ̀ dúró síbí pẹ̀lú mi, kí n bá à lè fún ọ ní àwọn àṣẹ tí o gbọdọ̀ fi kọ́ wọn láti máa tẹ̀lé ní ilẹ̀ náà tí èmi ó fi fún wọn láti ní.”


Aṣòfin àti onídàájọ́ kan ṣoṣo ní ó ń bẹ, àní ẹni tí ó lè gbàlà tí ó sì le parun, ṣùgbọ́n ta ni ìwọ tí ó ń dá ẹnìkejì rẹ lẹ́jọ́?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan