Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 21:13 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

13 Láti ibẹ̀ lọ, wọn ṣí, wọ́n sì dó sí ìhà kejì Arnoni, tí ó wà ní aginjù tí ó wà ní agbègbè ilẹ̀ àwọn ọmọ Amori. Arnoni jẹ́ ààlà fún ilẹ̀ Moabu, láàrín Moabu àti Amori.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

13 Wọ́n tún ṣí kúrò ní àfonífojì Seredi, wọ́n pa àgọ́ wọn sí òdìkejì odò Arinoni, tí ó wà ní aṣálẹ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ láti agbègbè àwọn ará Amori. Odò Arinoni jẹ́ ààlà ilẹ̀ Moabu, ó wà láàrin ilẹ̀ Moabu ati ilẹ̀ Amori.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

13 Lati ibẹ̀ lọ nwọn ṣí, nwọn si dó si ìha keji Arnoni, ti mbẹ li aginjù, ti o ti àgbegbe awọn ọmọ Amori wá: nitoripe Arnoni ni ipinlẹ Moabu, lãrin Moabu ati awọn Amori.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 21:13
8 Iomraidhean Croise  

Gẹ́gẹ́ bí alárìnkiri ẹyẹ tí a tì jáde kúrò nínú ìtẹ́, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn obìnrin Moabu ní àwọn ìwọdò Arnoni.


Ojú ti Moabu nítorí tí a wó o lulẹ̀. Ẹ hu, kí ẹ sì kígbe! Ẹ kéde rẹ̀ ní Arnoni pé, a pa Moabu run.


Ìdí nìyìí tí ìwé ogun Olúwa se wí pé: “…Wahebu ní Sufa, Òkun pupa àti ní odò Arnoni


Nígbà tí Balaki gbọ́ pé Balaamu ń bọ̀ wá, ó jáde lọ láti lọ pàdé rẹ̀ ní ìlú Moabu tí ó wà ní agbègbè Arnoni, ní ẹ̀gbẹ́ ilẹ̀ rẹ̀.


Olúwa sì wí pé, “Ẹ dìde, kí ẹ sì la Àfonífojì Seredi kọjá.” Bẹ́ẹ̀ ni a la àfonífojì náà kọjá.


“Lónìí ni ẹ̀yin yóò la agbègbè Moabu kọjá ní Ari.


“Ẹ gbáradì, kí ẹ sì kọjá odò Arnoni. Kíyèsi, Mo ti fi Sihoni ará Amori, ọba Heṣboni àti ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́. Ẹ bá ilẹ̀ náà jagun kí ẹ sì gbà á.


“Wọ́n rin aginjù kọjá, wọ́n pẹ́ àwọn ilẹ̀ Edomu àti ti Moabu sílẹ̀, nígbà tí wọ́n gba apá ìlà-oòrùn Moabu, wọ́n sì tẹ̀dó sí apá kejì Arnoni. Wọn kò wọ ilẹ̀ Moabu, nítorí pé ààlà rẹ̀ ni Arnoni wà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan