Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 20:2 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Omi kò sí fún ìjọ ènìyàn, àwọn ènìyàn sì kó ara wọn jọ pọ̀ sí Mose àti Aaroni,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Kò sí omi fún àwọn eniyan náà níbi tí wọ́n ṣe ibùdó sí, wọ́n sì kó ara wọn jọ sí Mose ati Aaroni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Omi kò si sí fun ijọ: nwọn si kó ara wọn jọ pọ̀ si Mose ati si Aaroni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 20:2
14 Iomraidhean Croise  

Níbi omi Meriba, wọ́n bí Ọlọ́run nínú, ohun búburú wá sí orí Mose nítorí wọn.


“Èmi ti gbọ́ kíkùn àwọn ọmọ Israẹli. Sọ fun wọn, ‘Ní àṣálẹ́, ẹ̀yin yóò jẹ ẹran, àti ni òwúrọ̀ ni ẹ̀yin yóò jẹ oúnjẹ. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ”


Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli sì ń kùn sí Mose àti Aaroni ní ijù náà.


Ní òwúrọ̀, ẹ̀yin yóò ri ògo Olúwa, nítorí òun ti gbọ́ kíkùn tí ẹ kùn sí i. Ta ni àwa ti ẹ̀yin yóò máa kùn sí wa?”


Gbogbo ọmọ Israẹli sì kùn sí Mose àti Aaroni, gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli sì wí fún wọn pé; “Àwa ìbá kúkú ti kú ní ilẹ̀ Ejibiti. Tàbí kí a kúkú kú sínú aginjù yìí.


Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa. Kí ẹ sì má bẹ̀rù àwọn ènìyàn ìlú náà, nítorí pé a ó gbé wọn mì, ààbò wọn ti fi wọ́n sílẹ̀, Olúwa sì wà pẹ̀lú àwa, Ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn.”


Nígbà tí Kora kó gbogbo àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ jọ sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, ògo Olúwa sì farahan gbogbo ìjọ ènìyàn.


Wọ́n kó ara wọn jọ láti tako Mose àti Aaroni, wọ́n sọ fún wọn pé, “Ẹ ti kọjá ààyè yín, ó tó gẹ́ẹ́! Mímọ́ ni gbogbo ènìyàn, kò sí ẹni tí kò mọ́ láàrín wọn, Olúwa sì wà pẹ̀lú wọn, nítorí kí wá ni ẹ̀yin ṣe gbé ara yín ga ju ìjọ ènìyàn Olúwa lọ?”


Ṣùgbọ́n nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn péjọ lòdì sí Mose àti Aaroni, níwájú àgọ́ ìpàdé, lójijì ni ìkùùkuu bolẹ̀, ògo Olúwa sì fi ara hàn.


wọ́n sì sọ̀rọ̀ lòdì sí Ọlọ́run àti Mose, wọ́n wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi mú wa jáde láti Ejibiti kí a ba le wá kú sí aginjù yìí? Kò sí oúnjẹ! Kò sì sí omi! Àwa sì kórìíra oúnjẹ tí kò dára yìí!”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan