Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 20:16 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 ṣùgbọ́n nígbà tí a sọkún sí Olúwa, ó gbọ́ ẹkún wa, ó sì rán angẹli kan sí wa, ó sì mú wa jáde láti Ejibiti. “Báyìí àwa wà ní Kadeṣi, ìlú tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ilẹ̀ rẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

16 Nígbà tí a ké pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́, ó gbọ́ adura wa, ó sì rán angẹli rẹ̀ láti mú wa jáde kúrò ní Ijipti. Nisinsinyii a ti dé Kadeṣi, ìlú kan tí ó wà lẹ́yìn odi agbègbè rẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

16 Nigbati awa si kepè OLUWA, o gbọ́ ohùn wa, o si rán angeli kan, o si mú wa lati Egipti jade wá; si kiyesi i, awa mbẹ ni Kadeṣi, ilu kan ni ipinlẹ àgbegbe rẹ:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 20:16
14 Iomraidhean Croise  

Bí Farao ti súnmọ́ tòsí ọ̀dọ̀ wọn, àwọn ọmọ Israẹli gbé ojú wọn sókè, wọn sì rí àwọn ará Ejibiti tó súnmọ́ wọn. Ẹ̀rù ńlá sì bá àwọn ará Israẹli, wọ́n kígbe sókè sí Olúwa.


Nígbà náà ni angẹli Ọlọ́run tó ti ń ṣáájú ogun Israẹli lọ, padà o sì rìn ni ẹ̀yìn wọn; Òpó ìkùùkuu tí ń rìn ni iwájú wọn sì padà sí í rìn ni ẹ̀yìn wọn.


“Kíyèsi èmi rán angẹli kan lọ ní iwájú rẹ, láti ṣọ́ ọ ni ọ̀nà àti láti mú ọ dé ibi ti mo ti pèsè sílẹ̀ fún.


Èmi yóò rán angẹli ṣáájú yín, èmi yóò sì lé àwọn Kenaani, àwọn ará Amori, àwọn ará Hiti, àwọn ará Peresi, àwọn ará Hifi àti àwọn ará Jebusi jáde.


Èmi sì ti tún gbọ́ kíkùn àwọn ọmọ Israẹli àwọn tí àwọn ará Ejibiti mú gẹ́gẹ́ bí ẹrú, àti pé èmi sì ti rántí májẹ̀mú Mi.


Ọlọ́run mi rán angẹli i rẹ̀, ó sì dí àwọn kìnnìún lẹ́nu. Wọn kò le è pa mí lára, nítorí a rí mi gẹ́gẹ́ bí aláìlẹ́ṣẹ̀ ní iwájú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò hu ìwà ìbàjẹ́ kan níwájú rẹ ìwọ ọba.”


Àwọn baba ńlá wa sọ̀kalẹ̀ wá sí Ejibiti, a sì gbé ibẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àwọn ará Ejibiti ni wá lára àti àwọn baba wa,


“Jẹ́ kí a kọjá ní orílẹ̀-èdè rẹ. A kò ní kọjá sí inú oko pápá tàbí ọgbà àjàrà àbí mu omi láti inú kànga. A máa gba òpópónà náà ti ọba títí tí a ó fi la ilẹ̀ rẹ kọjá.”


Wọ́n kúrò ní Kadeṣi wọ́n sì pàgọ́ ní orí òkè Hori, lẹ́bàá Edomu.


Ǹjẹ́ Ọlọ́run kan ti gbìyànjú àti mú orílẹ̀-èdè kan jáde kúrò nínú òmíràn fúnrarẹ̀ rí, nípa ìdánwò, nípa iṣẹ́ ààmì, àti iṣẹ́ ìyanu nípa ogun, tàbí nípa ọwọ́ agbára tàbí nína apá, àti nípa ẹ̀rù ńlá: gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Olúwa Ọlọ́run yín ṣe fún un yín ní Ejibiti ní ojú ẹ̀yin tìkára yín?


torí pé ó fẹ́ràn àwọn baba ńlá yín, ó sì yan àwọn ọmọ wọn ní ipò lẹ́yìn wọn. Nípa ìwà láààyè àti nípa agbára ńlá rẹ̀ ni ó fi mú un yín kúrò ní Ejibiti.


Ìpín fún ẹ̀yà Juda, ní agbo ilé agbo ilé, títí dé agbègbè Edomu, títí dé aginjù Sini ní òpin ìhà gúúsù.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan