Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 2:25 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

25 Ní ìhà àríwá: ni ìpín Dani yóò pa ibùdó sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Dani ni Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

25 Àsíá ibùdó ẹ̀yà Dani yóo wà ní ìhà àríwá ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí; Ahieseri, ọmọ Amiṣadai, ni yóo jẹ́ olórí wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

25 Ọpagun ibudó Dani ni ki o wà ni ìha ariwa gẹgẹ bi ogun wọn: Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Dani.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 2:25
7 Iomraidhean Croise  

Láti ọ̀dọ̀ Dani, Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai;


Láti ìran Dani: Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.


Lákòótan, àwọn ọmọ-ogun tó ń mójútó ẹ̀yìn ló tún kàn, àwọn ni ìpín ti ibùdó Dani lábẹ́ ọ̀págun wọn. Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai ni ọ̀gágun wọn.


Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá-mọ́kànlélọ̀gbọ̀n ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin. (62,700).


Olórí àwọn ìdílé ìran Merari ni Ṣurieli ọmọ Abihaili. Wọn yóò pa ibùdó wọn sí ìhà àríwá àgọ́.


Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai, olórí àwọn ọmọ Dani ni ó mú ọrẹ tirẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹwàá.


àti fún ẹbọ ti ẹbọ àlàáfíà, akọ màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún, akọ ọ̀dọ́-àgùntàn márùn-ún ọlọ́dún kan. Èyí ni ọrẹ ẹbọ tí Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan