Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 2:24 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

24 Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Efraimu, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rìnléláàdọ́ta ó-lé-ọgọ́rùn-ún (108,100). Àwọn ni yóò jáde sìkẹ́ta.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

24 Àpapọ̀ gbogbo àgọ́ Efuraimu ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí jẹ́ ọ̀kẹ́ marun-un ó lé ẹgbaarin ati ọgọrun-un (108,100). Àwọn ni wọn yóo jẹ́ ìpín kẹta tí àwọn ọmọ Israẹli bá fẹ́ ṣí láti ibùdó kan sí òmíràn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

24 Gbogbo awọn ti a kà ni ibudó Efraimu, jẹ́ ẹgba mẹrinlelãdọta o le ọgọrun, gẹgẹ bi ogun wọn. Awọn ni yio si ṣí ṣikẹta.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 2:24
6 Iomraidhean Croise  

Níwájú Efraimu, Benjamini àti Manase. Ru agbára rẹ̀ sókè; wá fún ìgbàlà wa.


Àwọn ìpín tó wà ní ibùdó Efraimu ló tún kàn lábẹ́ ọ̀págun wọn. Eliṣama ọmọ Ammihudu ni ọ̀gágun wọn.


Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Reubeni, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá-márùn-dínlọ́gọ́rin ó-lé-àádọ́ta-lé-légbéje (151,450). Àwọn ni yóò jáde sìkéjì.


Iye ìpín rẹ̀ ni ẹgbàá-mẹ́tà-dínlógún ó-lé-egbèje (35,400).


Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Dani jẹ́ ẹgbàá-méjì-dínlọ́gọ̀rin ó-lé-ẹgbẹ̀jọ (157,600). Àwọn ni yóò jáde kẹ́yìn lábẹ́ ọ̀págun wọn.


Gbogbo àwọn tí a yàn sí ibùdó Juda, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tàléláàdọ́run ó-lé-irínwó (186,400). Àwọn ni yóò kọ́kọ́ ṣáájú.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan