Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 2:2 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 “Kí àwọn ọmọ Israẹli pa àgọ́ wọn yí àgọ́ ìpàdé ká, kí wọ́n jẹ́ kí àgọ́ wọn jìnnà sí i díẹ̀, oníkálùkù lábẹ́ ọ̀págun pẹ̀lú àsíá ìdílé wọn.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli yóo bá pàgọ́ wọn, kí olukuluku máa pàgọ́ rẹ̀ lábẹ́ àsíá ẹ̀yà rẹ̀, ati lábẹ́ ọ̀págun ìdílé rẹ̀. Kí wọ́n máa pàgọ́ wọn yí Àgọ́ náà ká.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Ki olukuluku awọn ọmọ Israeli ki o pa agọ́ rẹ̀ lẹba ọpagun rẹ̀, pẹlu asia ile baba wọn: ki nwọn ki o pagọ́ kọjusi agọ́ ajọ yiká.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 2:2
23 Iomraidhean Croise  

Àwọn ọ̀tá rẹ ń bú ramúramù láàrín ènìyàn rẹ, wọ́n ń gbé àsíá wọn sókè fún ààmì;


Jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì mú un ṣẹ; kí gbogbo àwọn tí ó yí i ká mú ẹ̀bùn wá fún ẹni tí ó tọ́ láti bẹ̀rù.


Kígbe sókè kí o sì kọrin fún ayọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Sioni, nítorí títóbi ni ẹni mímọ́ kan ṣoṣo ti Israẹli láàrín yín.”


Gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ayé, tí ó ń gbé orílẹ̀ ayé, nígbà tí a bá gbé àsíá kan sókè lórí òkè, ẹ ó rí i, nígbà tí a bá fun fèrè kan ẹ ó gbọ́ ọ.


Ó sì wí pé: “Ọmọ ènìyàn, èyí yìí ni ibi ìgúnwà mi àti ibi tí ó wà fún àtẹ́lẹsẹ̀ mi, Ibi yìí ni èmi yóò máa gbé ní àárín àwọn ọmọ Israẹli títí láéláé. Ilé Israẹli kò ní ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mọ́ láéláé àwọn tàbí àwọn ọba wọn nípa àgbèrè àti àwọn ère aláìlẹ́mìí àwọn ọba wọn ní ibi gíga.


Olúwa Ọlọ́run wọn yóò sì gbà wọ́n là ni ọjọ́ náà bí agbo ènìyàn rẹ̀: nítorí wọn ó dàbí àwọn òkúta adé, tí a gbé sókè bí ààmì lórí ilẹ̀ rẹ̀.


Dípò èyí yan àwọn ọmọ Lefi láti jẹ́ alábojútó àgọ́ ẹ̀rí, lórí gbogbo ohun èlò àti ohun gbogbo tó jẹ́ ti àgọ́ ẹ̀rí. Àwọn ni yóò máa gbé àgọ́ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, wọn ó máa mójútó o, kí wọn ó sì máa pàgọ́ yí i ká.


Àwọn ìpín ti ibùdó Juda ló kọ́kọ́ gbéra tẹ̀lé wọn lábẹ́ ogun wọn Nahiṣoni ọmọ Amminadabu ni ọ̀gágun wọn.


Àwọn ìpín ti ibùdó ti Reubeni ló gbéra tẹ̀lé wọn, lábẹ́ ọ̀págun wọn. Elisuri ọmọ Ṣedeuri ni ọ̀gágun wọn.


Àwọn ìpín tó wà ní ibùdó Efraimu ló tún kàn lábẹ́ ọ̀págun wọn. Eliṣama ọmọ Ammihudu ni ọ̀gágun wọn.


Lákòótan, àwọn ọmọ-ogun tó ń mójútó ẹ̀yìn ló tún kàn, àwọn ni ìpín ti ibùdó Dani lábẹ́ ọ̀págun wọn. Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai ni ọ̀gágun wọn.


Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé:


Ní ìhà gúúsù: ni ìpín ti Reubeni pa ibùdó sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Reubeni ni Elisuri ọmọ Ṣedeuri.


Ní ìlà-oòrùn, ní ìdojúkọ àtiyọ oòrùn: ni kí ìpín ti Juda pa ibùdó wọn sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Juda ni Nahiṣoni ọmọ Amminadabu.


Nígbà tí Balaamu wo ìta ó sì rí Israẹli tí wọ́n pàgọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì bà sórí rẹ̀


Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run ohun rúdurùdu, ṣùgbọ́n ti àlàáfíà. Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ nínú gbogbo ìjọ ènìyàn mímọ́.


Ẹ máa ṣe ohun gbogbo tẹ̀yẹtẹ̀yẹ àti lẹ́sẹẹsẹ.


Ohun yówù kó ṣẹlẹ̀, ẹ jẹ́ kí ìgbé ayé yín ri gẹ́gẹ́ bí ìhìnrere Kristi: pé yálà bi mo tilẹ̀ wá wò yín, tàbí bí èmi kò wá, kí èmi kí ó lè máa gbúròó bí ẹ ti ń ṣe, pé ẹ̀yin dúró ṣinṣin nínú Ẹ̀mí kan, ẹ̀yin jùmọ̀ jìjàkadì nítorí ìgbàgbọ́ ìhìnrere, pẹ̀lú ọkàn kan;


Wọn ti sọ ìdàpọ̀ wọn pẹ̀lú ẹni tí i ṣe orí nu, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí a ń ti ipa oríkèé àti iṣan pèsè fún gbogbo ara, ti a sì ń so ó ṣọ̀kan pọ̀, tí ó sì ń dàgbà nípa ìmísí Ọlọ́run.


Ẹyin yóò lè mọ ọ̀nà tí ẹ ó gbà, torí pé ẹ̀yin kò gba ọ̀nà yìí tẹ́lẹ̀ rí. Ṣùgbọ́n àlàfo gbọdọ̀ wà ní àárín yín àti àpótí náà, tó bí ìwọ̀n ẹgbàá ìgbọ̀nwọ́.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan