Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 19:16 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá wà ní ìta tí ó sì fi ọwọ́ kan ẹni tí a fi idà pa tàbí ẹni tí ó kú ikú àtọ̀runwá, tàbí bí ẹnìkan bá fi ọwọ́ kan egungun òkú ènìyàn tàbí isà òkú, yóò jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

16 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ẹni tí wọ́n fi idà pa, tabi òkú, tabi egungun òkú tabi ibojì òkú ninu pápá yóo di aláìmọ́ fún ọjọ́ meje.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

16 Ẹnikẹni ti o ba si fọwọkàn ẹnikan ti a fi idà pa ni gbangba igbẹ́, tabi okú kan, tabi egungun ẹnikan, tabi isà-okú, yio jẹ́ alaimọ́ ni ijọ́ meje.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 19:16
12 Iomraidhean Croise  

Ẹ túká, ẹ túká, ẹ jáde kúrò níhìn-ín-yìí! Ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kan! Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ kí ẹ sì di mímọ́, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ohun èlò Olúwa.


Lẹ́yìn ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, ki òun kí ó dúró fún ọjọ́ méje.


Olúwa sọ fún Mose wí pe, “Bá àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Aaroni sọ̀rọ̀, kí o sì sọ fún wọn pé: ‘Ẹnikẹ́ni nínú wọn kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nítorí àwọn ènìyàn wọn tí ó kù.


“Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú ẹnikẹ́ni, yóò jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje.


Gbogbo ohun èlò tí a kò bá fi omọrí dé ni yóò jẹ́ aláìmọ́.


“Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti pa ènìyàn tàbí fọwọ́ kan ẹni tí a pa gbọdọ̀ dúró ní ìta ibùdó àgọ́ fún ọjọ́ méje, Ní ọjọ́ kẹta àti ọjọ́ keje ẹ gbọdọ̀ ya ara yín àti ẹni tí ẹ kó lẹ́rú sí mímọ́.


“Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọn ó lé ẹnikẹ́ni tó bá ní ẹ̀tẹ̀, ìtújáde ara ní oríṣìíríṣìí tàbí ẹni tó jẹ́ aláìmọ́ nípa fífọwọ́ kan òkú.


“ ‘Ní gbogbo àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ sí Olúwa kò gbọdọ̀ súnmọ́ òkú ènìyàn.


Àwọn díẹ̀ nínú wọn kò lè ṣe àjọ Ìrékọjá lọ́jọ́ náà nítorí pé wọ́n di aláìmọ́ nítorí òkú ènìyàn. Nítorí èyí wọ́n wá sọ́dọ̀ Mose àti Aaroni lọ́jọ́ náà.


“Ègbé ni fún yín ẹ̀yin Farisi àti ẹ̀yin olùkọ́ òfin, ẹ̀yin àgàbàgebè. Ẹ dàbí ibojì funfun tí ó dára ní wíwò, ṣùgbọ́n tí ó kún fún egungun ènìyàn àti fún ẹ̀gbin àti ìbàjẹ́.


“Ègbé ni fún un yín, (ẹ̀yin akọ̀wé àti ẹ̀yin Farisi àgàbàgebè) nítorí ẹ̀yin dàbí ibojì tí kò farahàn, tí àwọn ènìyàn sì ń rìn lórí rẹ̀ láìmọ̀.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan