Numeri 18:21 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní21 “Mó ti fún àwọn ọmọ Lefi ní gbogbo ìdámẹ́wàá ní Israẹli gẹ́gẹ́ bí ogún fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣe, nígbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ níbi àgọ́ ìpàdé Faic an caibideilYoruba Bible21 OLUWA wí pé, “Mo ti fún àwọn ọmọ Lefi ní gbogbo ìdámẹ́wàá tí àwọn ọmọ Israẹli bá mú wá fún mi gẹ́gẹ́ bí ìní wọn fún iṣẹ́ ìsìn wọn ninu Àgọ́ Àjọ. Faic an caibideilBibeli Mimọ21 Si kiyesi i, emi si ti fi gbogbo idamẹwa ni Israeli fun awọn ọmọ Lefi ni iní, nitori iṣẹ-ìsin wọn ti nwọn nṣe, ani iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ. Faic an caibideil |
“Síwájú sí i, àwa yóò mú àkọ́so oúnjẹ ilẹ̀ wa ti ọrẹ oúnjẹ, ti gbogbo èso àwọn igi àti ti wáìnì tuntun wa àti ti òróró wá sí yàrá ìkó-nǹkan-pamọ́-sí ilé Ọlọ́run wa àti fún àwọn àlùfáà. Àwa yóò sì mú ìdámẹ́wàá ohun ọ̀gbìn wá fún àwọn ọmọ Lefi, nítorí àwọn ọmọ Lefi ni ó ń gba ìdámẹ́wàá ní gbogbo àwọn ìlú tí a ti ń ṣiṣẹ́.
Ní àkókò náà, a yan àwọn ènìyàn láti jẹ́ alábojútó yàrá ìṣúra fún àwọn ọrẹ àkọ́so èso àti àwọn ìdámẹ́wàá. Láti inú àwọn oko tí ó wà ní àyíká ìlú ni wọ́n ti ní láti mú wá sínú yàrá ìṣúra, ìpín tí òfin sọ fún àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, nítorí inú àwọn ará a Juda yọ́ sí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi tó ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́.