Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 18:16 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 Nígbà tí wọ́n bá pé oṣù kan, o gbọdọ̀ rà wọ́n padà ní iye owó ìràpadà tí í ṣe ṣékélì márùn-ún fàdákà, gẹ́gẹ́ bí iye ṣékélì ibi mímọ́ tí ó wọn ìwọ̀n ogún (20) gera.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

16 Àwọn òbí yóo ra àwọn ọmọ wọn pada nígbà tí wọ́n bá pé ọmọ oṣù kan. Owó ìràpadà wọn jẹ́ ìwọ̀n ṣekeli marun-un. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́, èyí tíí ṣe ogún ìwọ̀n gera ni kí wọ́n fi wọ̀n ọ́n.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

16 Gbogbo awọn ti a o ràsilẹ, lati ẹni oṣù kan ni ki iwọ ki o ràsilẹ, gẹgẹ bi idiyelé rẹ, li owo ṣekeli marun, nipa ṣekeli ibi-mimọ́ (ti o jẹ́ ogun gera).

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 18:16
9 Iomraidhean Croise  

Olúkúlùkù ẹrù tí ó bá kọjá lọ sọ́dọ̀ àwọn tí a ti kà yóò san ìdajì ṣékélì, gẹ́gẹ́ bí ṣékélì ibi mímọ́, èyí tí ó wọn ogún gera. Ìdajì ṣékélì yìí ní ọrẹ fún Olúwa.


Àròpọ̀ iye wúrà lára wúrà ọrẹ tí a lò fún gbogbo iṣẹ́ ibi mímọ́ náà jẹ́ tálẹ́ǹtì mọ́kàn-dínlọ́gbọ̀n àti ẹgbẹ̀rin ṣékélì gẹ́gẹ́ bí i ṣékélì ibi mímọ́.


Ṣékélì ní kí o gba ogún gera. Ogún ṣékélì pẹ̀lú ṣékélì márùn-dínlọ́gbọ̀n pẹ̀lú ṣékélì mẹ́ẹ̀ẹ́dógún yóò jẹ́ minas kan.


Gbogbo iye owó wọ̀nyí gbọdọ̀ wà ní ìbámu pẹ̀lú ṣékélì ibi mímọ́, ogún gera.


Gbogbo àkọ́bí nínú gbogbo ohun alààyè tí wọ́n mú wá fún Olúwa, ìbá à jẹ́ ti ènìyàn tàbí ti ẹranko jẹ́ tìrẹ ṣùgbọ́n o gbọdọ̀ ra gbogbo àkọ́bí ọmọkùnrin padà àti àkọ́bí àwọn ẹranko aláìmọ́.


“Ṣùgbọ́n o kò gbọdọ̀ ra àwọn àkọ́bí ọmọ màlúù, àgùntàn tàbí ewúrẹ́; wọ́n jẹ́ mímọ́. Wọ́n ẹ̀jẹ̀ wọn sórí pẹpẹ kí o sì sun ọ̀rá rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àfinásun, ẹbọ òórùn dídùn sí Olúwa.


Nísinsin yìí, láti lè ra ọ̀rìnlúgba dín méje (273) àkọ́bí àwọn Israẹli tó ju iye àwọn ọmọ Lefi lọ,


ìwọ yóò gba ṣékélì márùn-ún (5) lórí ẹni kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, èyí tí í ṣe ogún gera.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan