Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 17:2 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí o sì gba ọ̀pá méjìlá lọ́wọ́ wọn, ọ̀kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ olórí ìdílé ẹ̀yà ìran wọn, kọ orúkọ ènìyàn kọ̀ọ̀kan sí ara ọ̀pá rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 “Gba ọ̀pá mejila láti ọwọ́ àwọn ọmọ Israẹli, ọ̀pá kọ̀ọ̀kan láti ọwọ́ olórí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, kí o sì kọ orúkọ olukuluku sí ara ọ̀pá tirẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si gbà ọpá kọkan lọwọ wọn, gẹgẹ bi ile awọn baba wọn, lọwọ gbogbo awọn olori wọn gẹgẹ bi ile awọn baba wọn ọpá mejila: ki o si kọ́ orukọ olukuluku si ara ọpá rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 17:2
18 Iomraidhean Croise  

Ọ̀pá oyè kì yóò kúrò ní Juda bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá-ìṣàkóso kì yóò kúrò láàrín ẹsẹ̀ rẹ̀, títí tí Ṣilo tí ó ni í yóò fi dé, tí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò máa wárí fún un.


Wọ́n sì pín àwọn àlùfáà, wọn kọ orúkọ àwọn ìdílé wọn sínú ìtàn ìdílé àti sí àwọn ará Lefi ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu àti ìpín wọn.


Olúwa yóò na ọ̀pá agbára rẹ̀ láti Sioni wá, ìwọ jẹ ọba láàrín àwọn ọ̀tá rẹ.


Nítorí tí ọ̀pá àwọn ènìyàn búburú kì yóò bà lé ìpín àwọn olódodo; kí àwọn olódodo kí ó máa ba à fi ọwọ́ wọn lé ẹ̀ṣẹ̀.


Ìwọ yóò sì lò ó láti ya àgọ́ sí mímọ́ àti àpótí ẹ̀rí náà,


Ṣùgbọ́n mú ọ̀pá yìí ni ọwọ́ rẹ kí ìwọ bá à lè fi ṣe àwọn iṣẹ́ ààmì ìyanu pẹ̀lú rẹ̀.”


Ní ìgbà náà ni Olúwa sọ fún un pé, “Kí ni ó wà ní ọwọ́ rẹ n nì?” Ó sì dáhùn pé, “ọ̀pá ni.”


Iná sì jáde láti ọ̀kan lára ẹ̀ka rẹ̀ ó sì pa ẹ̀ka àti èso rẹ̀ run, dé bi pé kò sí ẹ̀ka tó lágbára lórí rẹ̀ mọ́; èyí to ṣe fi ṣe ọ̀pá fún olórí mọ́.’ Èyí ni orin ọ̀fọ̀ a o sì máa lo bí orin ọ̀fọ̀.”


a pọ́n láti pa ènìyàn púpọ̀, a dán an láti máa kọ mọ̀nà! “ ‘Àwa o ha máa ṣe àríyá ọ̀gọ ọmọ mi? Idà gán gbogbo irú igi bẹ́ẹ̀.


“ ‘Ìdánwò yóò dé dandan. Tí ọ̀pá aládé Juda èyí tí idà kẹ́gàn, kò bá tẹ̀síwájú mọ́ ńkọ́? Ni Olúwa Olódùmarè wí.’


Fi ọ̀pá rẹ bọ́ àwọn ènìyàn, agbo ẹran ìní rẹ, èyí tí ó ń dágbé nínú igbó ní àárín Karmeli; Jẹ́ kí wọn jẹun ní Baṣani àti Gileadi bí ọjọ́ ìgbàanì.


Olúwa sì sọ fún Mose pé,


Lórí ọ̀pá Lefi kọ orúkọ Aaroni, nítorí ọ̀pá kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ wà fún olórí ìdílé kọ̀ọ̀kan tí yóò jẹ́ orí fún ẹ̀yà ìran kọ̀ọ̀kan.


Nígbà tí Mose ti parí gbígbé àgọ́ dúró, ó ta òróró sí i, ó sì yà á sí mímọ́ pẹ̀lú gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀, Ó tún ta òróró sí pẹpẹ, ó sì yà á sí mímọ́ pẹ̀lú gbogbo ohun èlò rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan