Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 16:42 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

42 Ṣùgbọ́n nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn péjọ lòdì sí Mose àti Aaroni, níwájú àgọ́ ìpàdé, lójijì ni ìkùùkuu bolẹ̀, ògo Olúwa sì fi ara hàn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

42 Ó sì ṣe nígbà tí àwọn eniyan náà kó ara wọn jọ láti dojú kọ Mose ati Aaroni, wọn bojúwo ìhà Àgọ́ Àjọ, wọ́n sì rí i tí ìkùukùu bò ó, ògo OLUWA sì farahàn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

42 O si ṣe, nigbati ijọ pejọ pọ̀ si Mose ati si Aaroni, ti nwọn si wò ìha agọ́ ajọ: si kiyesi i, awọsanma bò o, ogo OLUWA si farahàn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 16:42
10 Iomraidhean Croise  

Ó sì ṣe bí Aaroni ti ń bá gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀, wọn si bojú wo ìhà ijù, sì kíyèsi ògo Olúwa si farahàn ni àwọsánmọ̀.


Ní òwúrọ̀, ẹ̀yin yóò ri ògo Olúwa, nítorí òun ti gbọ́ kíkùn tí ẹ kùn sí i. Ta ni àwa ti ẹ̀yin yóò máa kùn sí wa?”


Ògo Olúwa sì wà ní orí òkè Sinai. Ìkùùkuu bo orí òkè náà fún ọjọ́ mẹ́fà, ni ọjọ́ keje ni Olúwa kọ sí Mose láti inú ìkùùkuu náà wá.


Mose àti Aaroni sì wọ inú àgọ́ ìpàdé. Nígbà tí wọ́n jáde, wọ́n súre fún àwọn ènìyàn, ògo Olúwa sì farahàn sí gbogbo ènìyàn,


Ṣùgbọ́n gbogbo ìjọ ènìyàn sì ń sọ pé àwọn yóò sọ wọ́n lókùúta pa. Nígbà náà ni ògo Olúwa fi ara hàn ní àgọ́ ìpàdé níwájú àwọn ọmọ Israẹli.


Nígbà tí Kora kó gbogbo àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ jọ sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, ògo Olúwa sì farahan gbogbo ìjọ ènìyàn.


Nígbà náà ni Mose àti Aaroni lọ síwájú àgọ́ ìpàdé,


Omi kò sí fún ìjọ ènìyàn, àwọn ènìyàn sì kó ara wọn jọ pọ̀ sí Mose àti Aaroni,


Mose àti Aaroni kúrò ní ibi àpéjọ, wọ́n sì lọ dojúbolẹ̀ sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, ògo Olúwa sì farahàn wọ́n.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan