Numeri 16:22 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní22 Ṣùgbọ́n Mose àti Aaroni dojúbolẹ̀ wọ́n sì kígbe sókè pé, “Ọlọ́run, Ọlọ́run ẹ̀mí gbogbo ènìyàn, Ìwọ ó wa bínú sí gbogbo ìjọ ènìyàn nígbà tó jẹ́ pé ẹnìkan ló ṣẹ̀?” Faic an caibideilYoruba Bible22 Mose ati Aaroni bá dojúbolẹ̀, wọ́n gbadura sí OLUWA, pé, “Ọlọrun, ìwọ ni orísun ìyè, ìwọ yóo ha tìtorí ẹ̀ṣẹ̀ ẹnìkan bínú sí gbogbo ìjọ eniyan bí?” Faic an caibideilBibeli Mimọ22 Nwọn si doju wọn bolẹ, nwọn wipe, Ọlọrun, Ọlọrun ẹmi gbogbo enia, ọkunrin kan ha le ṣẹ̀, ki iwọ ki o si binu si gbogbo ijọ? Faic an caibideil |
Mose sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù, Eleasari àti Itamari pé, “ẹ má ṣe ṣọ̀fọ̀ nípa ṣíṣe aláìtọ́jú irun yín tàbí kí ẹ ṣí orí yín sílẹ̀, ẹ kò sì gbọdọ̀ ya aṣọ, bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó kùú, Olúwa yóò sì bínú sí gbogbo ìjọ ènìyàn. Ṣùgbọ́n àwọn ẹbí yín, àti gbogbo ilé Israẹli le è ṣọ̀fọ̀ lórí àwọn tí Olúwa fi iná parun.