Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 16:18 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

18 Nígbà náà ni oníkálùkù wọn mú àwo tùràrí, wọ́n fi iná àti tùràrí sí i nínú, wọ́n sì dúró sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, àwọn pẹ̀lú Mose àti Aaroni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

18 Olukuluku wọn sì mú àwo turari tirẹ̀, wọ́n fi ẹ̀yinná ati turari sí i, wọ́n sì dúró ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ pẹlu Mose ati Aaroni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

18 Olukuluku wọn si mú awo-turari rẹ̀, nwọn si fi iná sinu wọn, nwọn si fi turari lé ori wọn, nwọn si duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, pẹlu Mose ati Aaroni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 16:18
7 Iomraidhean Croise  

Yóò sì mú àwo tùràrí tí ó kún fún èédú tí a ti sun pẹ̀lú iná láti orí pẹpẹ wá síwájú Olúwa: àti ẹ̀kúnwọ́ méjì tùràrí tí a gún kúnná yóò sì mú un wá sí ẹ̀yìn aṣọ títa.


Kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín mú àwo tùràrí, kí ó sì fi tùràrí sínú rẹ̀, kí gbogbo rẹ̀ jẹ́ àádọ́tà-lé-nígba àwo tùràrí (250) kí ẹ sì ko wá síwájú Olúwa. Ìwọ àti Aaroni yóò mú àwo tùràrí wá pẹ̀lú.”


Nígbà tí Kora kó gbogbo àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ jọ sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, ògo Olúwa sì farahan gbogbo ìjọ ènìyàn.


Yóò sì fi tùràrí náà lé orí iná níwájú Olúwa: kí èéfín tùràrí náà ba à le bo ìtẹ́ àánú tí ó wà ní orí àpótí ẹ̀rí kí o má ba à kú.


“Sọ fún Eleasari ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà, pé kí ó mú àwọn àwo tùràrí jáde kúrò nínú iná nítorí pé wọ́n jẹ́ mímọ́, kí ó sì tan iná náà káàkiri sí ibi tó jìnnà.


Ó dúró láàrín àwọn alààyè àti òkú, àjàkálẹ̀-ààrùn náà sì dúró.


Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí Ussiah jẹ́ alágbára tán, ìgbéraga rẹ̀ sì gbé e ṣubú. Ó sì di aláìṣòótọ́ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀. Ó sì wọ ilé Olúwa láti sun tùràrí lórí pẹpẹ tùràrí.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan