Numeri 15:16 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní16 Òfin kan àti ìlànà kan ni yóò wà fún yín àti fún àwọn àlejò tí ń gbé láàrín yín.’ ” Faic an caibideilYoruba Bible16 Òfin ati ìlànà kan náà ni yóo wà fún ẹ̀yin ati àjèjì tí ń gbé pẹlu yín.” Faic an caibideilBibeli Mimọ16 Ofin kan ati ìlana kan ni ki o wà fun nyin, ati fun alejò ti nṣe atipo lọdọ nyin. Faic an caibideil |
Gbogbo Israẹli, àjèjì àti ọmọ ìlú, pẹ̀lú àwọn àgbàgbà, olórí àti onídàájọ́ dúró ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì àpótí ẹ̀rí Olúwa tí ó kọjú sí àwọn àlùfáà tí ó rù ú, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi. Ìdajì àwọn ènìyàn náà dúró ní Òkè Gerisimu, àwọn ìdajì si dúró ni òkè Ebali, gẹ́gẹ́ bí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti pàṣẹ rí, pé kí wọn súre fún àwọn ènìyàn Israẹli.