Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 14:8 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Bí inú Olúwa bá dùn sí wa, yóò mú wa dé ilẹ̀ náà, ilẹ̀ tó ń sàn fún wàrà àti fún oyin, yóò fún wa ní ilẹ̀ náà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 Bí inú OLUWA bá dùn sí wa, yóo mú wa dé ilẹ̀ náà, yóo sì fún wa; àní ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati fún oyin, ilẹ̀ ọlọ́ràá tí ó lẹ́tù lójú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Bi OLUWA ba fẹ́ wa, njẹ yio mú wa wọ̀ inu ilẹ na yi, yio si fi i fun wa; ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 14:8
15 Iomraidhean Croise  

Ó sì mú mi wá sí ààyè ńlá: ó gbà mi, nítorí tí inú rẹ̀ dún sí mi.


Ìbùkún ni fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó ní inú dídùn sí ọ, tí ó sì gbé ọ ka orí ìtẹ́ Israẹli. Nítorí tí Olúwa fẹ́ràn Israẹli títí láé, ni ó ṣe fi ọ́ jẹ ọba, láti ṣe ìdájọ́ àti òdodo.”


Títí tí èmi yóò fi wá mú ọ lọ sí ilé gẹ́gẹ́ bí i tìrẹ, ilẹ̀ ọkà àti ọtí wáìnì, ilẹ̀ oúnjẹ àti ọgbà àjàrà, ilẹ̀ òróró olifi àti ti ilẹ̀ oyin; yàn ìyè má sì ṣe yàn ikú! “Kí ẹ má ṣe gbọ́ tí Hesekiah, nítorí ó ń tàn yín tí ó ba tí wí pé, ‘Olúwa yóò gbà wá?’


“Ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé Olúwa; jẹ́ kí Olúwa gbà á là. Jẹ́ kí ó gbà á là, nítorí pé, ó ní ayọ̀ nínú rẹ̀.”


Èmi sì ti sọ̀kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Ejibiti, àti láti mú wọn gòkè kúrò ní ilẹ̀ náà lọ sí ilẹ̀ tí ó dára tí ó sì ní ààyè, àní ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin; ibùgbé àwọn ará Kenaani, ará Hiti, Amori, Peresi, Hifi àti Jebusi.


Wọn kì yóò pè ọ́ ní ìkọ̀sílẹ̀ mọ́ tàbí kí wọ́n pe ilẹ̀ rẹ ní ahoro. Ṣùgbọ́n a ó máa pè ọ́ ní Hẹfsiba, àti ilẹ̀ rẹ ní Beula; nítorí Olúwa yóò yọ́nú sí ọ àti ilẹ̀ rẹ ni a ó gbé níyàwó.


Lóòtítọ́, èmi ó yọ̀ nípa ṣíṣe wọ́n ní rere, èmi ó sì fi dá wọn lójú nípa gbígbìn wọ́n sí ilẹ̀ yìí tọkàntọkàn mi.


Olúwa Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ, Ó ní agbára láti gbà ọ là. Yóò yọ̀ ni orí rẹ fún ayọ̀; Yóò tún ọ ṣe nínú ìfẹ́ rẹ̀, Yóò sì fi orin yọ̀ ní orí rẹ.”


Wọ́n sì fún Mose ní ìròyìn báyìí: “A lọ sí ilẹ̀ ibi tí o rán wa, lóòtítọ́ ló sì ń sàn fún wàrà àti fún oyin! Èso ibẹ̀ nìyìí.


Síbẹ̀síbẹ̀ ìwọ kò sì tí ì mú wa dé ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, bẹ́ẹ̀ ni o kò sì pín ilẹ̀ ìní àti ọgbà àjàrà. Ìwọ ha fẹ́ sọ wá di ẹrú bí? Rárá o, àwa kì yóò gòkè wá!”


Kí ni àwa yóò wí nísinsin yìí sí nǹkan ìyanu wọ̀nyí? Bí Ọlọ́run bá wà pẹ̀lú wa, ta ni yóò kọjú ìjà sí wa?


Síbẹ̀ Olúwa sì tún fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn fún àwọn baba ńlá a yín, Ó sì fẹ́ wọn Ó sì yan ẹ̀yin ọmọ wọn láti borí gbogbo orílẹ̀-èdè títí di òní.


Nísinsin yìí fi ìlú orí òkè fún mi èyí tí Olúwa ṣe ìlérí fún mi ní ọjọ́ náà. Ìwọ gbọ́ ní ìgbà náà pé àwọn ọmọ Anaki ti wà ní ibẹ̀, àti àwọn ìlú wọn tóbi, pé ó sì ṣe olódi, ṣùgbọ́n bí Olúwa ba fẹ́, èmi yóò lé wọn jáde, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan