Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 13:2 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 “Rán ènìyàn díẹ̀ láti lọ yẹ ilẹ̀ Kenaani wò èyí tí mo ti fún àwọn ọmọ Israẹli. Rán ẹnìkọ̀ọ̀kan, tí ó jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 “Rán amí lọ wo ilẹ̀ Kenaani tí mo fún àwọn ọmọ Israẹli. Ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ó bá jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ni kí o rán.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Rán enia, ki nwọn ki o si ṣe amí ilẹ Kenaani, ti mo fi fun awọn ọmọ Israeli: ọkunrin kan ni ki ẹnyin ki o rán ninu ẹ̀ya awọn baba wọn, ki olukuluku ki o jẹ́ ijoye ninu wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 13:2
12 Iomraidhean Croise  

Mose sì yan àwọn ènìyàn tí wọ́n kún ojú òṣùwọ̀n nínú gbogbo Israẹli; ó sì fi wọ́n jẹ olórí àwọn ènìyàn, olórí ẹgbẹẹ̀rún, olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún, olórí àràádọ́ta, àti olórí mẹ́wàá mẹ́wàá.


Kí ẹ mú ọkùnrin kọ̀ọ̀kan láti inú olúkúlùkù ẹ̀yà kí ó sì wá pẹ̀lú yín, kí olúkúlùkù jẹ́ olórí ilé àwọn baba rẹ̀.


Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé: “Mú àádọ́rin (70) ọkùnrin nínú àwọn àgbàgbà àwọn ọmọ Israẹli, àwọn tí o mọ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí àti olóyè láàrín àwọn ènìyàn wá sínú àgọ́ ìpàdé, kí wọ́n lé dúró níwájú mi.


Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ènìyàn tí Mose rán láti lọ yẹ ilẹ̀ náà wò. (Hosea ọmọ Nuni ni Mose sọ ní Joṣua.)


Mose sì rán wọn jáde láti Aginjù Parani gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa. Gbogbo wọn jẹ́ olórí àwọn ènìyàn Israẹli.


Èyí ni nǹkan tí baba yín ṣe nígbà tí mo rán wọn láti Kadeṣi-Barnea láti lọ wo ilẹ̀ náà.


Kí o sì yan olórí kan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan láti pín ilẹ̀ náà.


Bẹ́ẹ̀ ni mo yan olórí àwọn ẹ̀yà yín, àwọn ọlọ́gbọ́n ọkùnrin, ẹni àpọ́nlé, mo sì fi jẹ olórí yín: olórí ẹgbẹẹ̀rún, olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún, olórí àràádọ́ta, àti olórí mẹ́wàá mẹ́wàá gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀yà yín.


Nígbà tí Olúwa ran an yín jáde ní Kadeṣi-Barnea, Ó wí pé, “Ẹ gòkè lọ, kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà tí mo fi fún un yín.” Ṣùgbọ́n ẹ ṣọ̀tẹ̀ sí òfin Olúwa Ọlọ́run yín. Ẹ kò gbẹ́kẹ̀lé e, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọ́ tirẹ̀.


Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ mú ọkùnrin méjìlá nínú àwọn ẹ̀yà Israẹli, ẹnìkan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan