Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 12:8 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Mo sì ń bá a sọ̀rọ̀ ní ojúkojú, ọ̀rọ̀ yékéyéké tí kì í ṣe òwe, ó rí àwòrán Olúwa Kí ló wá dé tí ẹ̀yin kò ṣe bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀-òdì sí Mose ìránṣẹ́ mi?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 Lojukooju ni èmi í máa bá a sọ̀rọ̀; ọ̀rọ̀ ketekete sì ni, kì í ṣe àdììtú ọ̀rọ̀. Kódà, òun a máa rí ìrísí OLUWA. Kí ló dé tí ẹ kò fi bẹ̀rù ati sọ̀rọ̀ òdì sí i?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 On li emi mbá sọ̀rọ li ẹnu ko ẹnu, ati ni gbangba, ki si iṣe li ọ̀rọ ti o ṣe òkunkun; apẹrẹ OLUWA li on o si ri: njẹ nitori kili ẹnyin kò ṣe bẹ̀ru lati sọ̀rọ òdi si Mose iranṣẹ mi?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 12:8
39 Iomraidhean Croise  

Jakọbu sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Penieli pé, “Mo rí Ọlọ́run ní ojúkojú, síbẹ̀ a dá ẹ̀mí mi sí.”


Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi yóò máa wo ojú rẹ ní òdodo; nígbà tí èmi bá jí, èmi yóò ní ìtẹ́lọ́rùn nígbà tí èmi bá rí àwòrán rẹ.


Èmi yóò dẹ etí mi sílẹ̀ sí òwe, èmi yóò ṣí ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ mi sílẹ̀ lójú okùn dùùrù.


Ohùn ìpè sì ń rinlẹ̀ dòdò. Mose sọ̀rọ̀, Ọlọ́run sì fi àrá dá a lóhùn.


Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ère fún ara yín, tàbí àwòrán ohun kan tí ń bẹ ní òkè ọ̀run, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ nínú omi ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀.


Olúwa máa ń bá Mose sọ̀rọ̀ lójúkojú, gẹ́gẹ́ bí i pé ènìyàn ń bá ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Nígbà náà ni Mose yóò tún padà lọ sí ibùdó, ṣùgbọ́n ọ̀dọ́mọkùnrin Joṣua ìránṣẹ́ rẹ̀ ọmọ Nuni kò fi àgọ́ sílẹ̀.


Olúwa sì wí pé, “Èmi yóò sì mú gbogbo ìre mí kọjá níwájú rẹ, Èmi yóò sì pòkìkí orúkọ Olúwa níwájú rẹ. Èmi yóò ṣàánú fún ẹni tí èmi yóò ṣàánú fún, èmi yóò sì ṣoore-ọ̀fẹ́ fún ẹni tí èmi yóò ṣoore-ọ̀fẹ́ fún.


Nígbà tí èmi yóò mú ọwọ́ mi kúrò, ìwọ yóò sì rí ẹ̀yìn mi; ṣùgbọ́n ojú mi ni o kò ní rí.”


Nígbà tí Aaroni àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli rí Mose, ojú rẹ̀ ń dán, ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti súnmọ́ ọn.


Láti mọ ìtumọ̀ òwe àti ìtán-dòwe, àwọn ọ̀rọ̀ àti àlọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n.


Ta ni nígbà náà tí ìwọ yóò fi Ọlọ́run wé? Ère wo ni ìwọ yóò fi ṣe àkàwé rẹ̀?


“Ta ni ìwọ yóò fi mí wé tàbí ta ni èmi yóò bá dọ́gba? Ta ni ìwọ yóò fi ṣe àkàwé mi tí àwa yóò jọ fi ara wé ara?


“Ọmọ ènìyàn pa àlọ́ kan, sì pa òwe kan fún ilé Israẹli.


Nígbà náà ni mo wí pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè! Wọn ń wí fún mi pé, ‘Kì í wa ṣe pé òwe lo ń pa bí?’ ”


Olúwa lo wòlíì kan láti mú Israẹli jáde wá láti Ejibiti, nípasẹ̀ wòlíì kan ó ṣe ìtọ́jú rẹ̀.


Wọ́n ó sì sọ fún àwọn olùgbé ilẹ̀ yìí. Àwọn tó ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé ìwọ Olúwa wà láàrín àwọn ènìyàn wọ̀nyí àti pé wọ́n rí ìwọ, Olúwa, ní ojúkojú, àti pé ìkùùkuu àwọsánmọ̀ rẹ dúró lórí wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sì ń lọ níwájú wọn pẹ̀lú ìkùùkuu àwọsánmọ̀ ní ọ̀sán àti pẹ̀lú ọ̀wọ́n iná ní òru.


Nígbà tí Mose wọ inú àgọ́ ìpàdé láti bá Olúwa sọ̀rọ̀, Olúwa sì sọ̀rọ̀ sí i láti àárín àwọn kérúbù méjì láti orí ìtẹ́ àánú tí ó bo àpótí ẹ̀rí, ohùn náà sì bá Mose sọ̀rọ̀.


Kí ọ̀rọ̀ tí a ti ẹnu àwọn wòlíì sọ lé wá sí ìmúṣẹ pé: “Èmi yóò ya ẹnu mi láti fi òwe sọ̀rọ̀. Èmi yóò sọ àwọn ohun tí ó fi ara sin láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá.”


“Ẹni tí ó bá gbọ́ tiyín, ó gbọ́ tèmi. Ẹni tí ó bá sì kọ̀ yín, ó kọ̀ mi. Ẹni tí ó bá sì kọ̀ mi, ó kọ ẹni tí ó rán mi.”


Kò sí ẹni tí ó rí Ọlọ́run rí, bí kò ṣe òun nìkan, àní ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo, ẹni tí òun pàápàá jẹ́ Ọlọ́run, tí ó sì wà ní ìbásepọ̀ tí ó súnmọ́ jùlọ pẹ̀lú baba, òun náà ni ó sì fi í hàn.


Èmi kò pè yín ní ọmọ ọ̀dọ̀ mọ́; nítorí ọmọ ọ̀dọ̀ kò mọ ohun tí olúwa rẹ̀ ń ṣe: ṣùgbọ́n èmi pè yín ní ọ̀rẹ́ nítorí ohun gbogbo tí mo ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá, mo ti fihàn fún yín.


Ìbá ṣe pé èmi kò ti ṣe iṣẹ́ wọ̀n-ọn-nì láàrín wọn tí ẹlòmíràn kò ṣe rí, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀: ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n sì rí, wọ́n sì kórìíra èmi àti Baba mi.


Nítorí pé nísinsin yìí àwa ń ríran bàìbàì nínú dígí; nígbà náà a ó rí í lójúkojú. Nísinsin yìí mò mọ̀ pé ní apá kan; nígbà náà èmi o mọ̀ lẹ́kùnrẹ́rẹ́, kódà bí mo ti dí mí mọ̀ pẹ̀lú.


Ṣùgbọ́n gbogbo wa ń wo ògo Olúwa láìsí ìbòjú bí ẹni pé nínú àwòjìji, a sì ń pa wa dà sí àwòrán kan náà láti ògo dé ògo, àní bí láti ọ̀dọ̀ Olúwa tí í ṣe Ẹ̀mí.


Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò gbé wòlíì kan dìde gẹ́gẹ́ bí èmi láàrín àwọn arákùnrin rẹ. Tìrẹ ni kí o gbọ́.


Láti ìgbà náà kò sì sí wòlíì tí ó dìde ní Israẹli bí i Mose, ẹni tí Olúwa mọ̀ lójúkojú,


Ẹ kíyèsára gidigidi, torí pé, ẹ kò rí ìrísí ohunkóhun ní ọjọ́ tí Olúwa bá yín sọ̀rọ̀ ní Horebu láti àárín iná wá. Torí náà ẹ ṣọ́ra yín gidigidi,


Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ère fún ara yín, tàbí àwòrán ohun kan tí ń bẹ ní òkè ọ̀run, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ nínú omi ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀.


Kristi ni àwòrán Ọlọ́run tí a kò le rí, àkọ́bí gbogbo ẹ̀dá.


Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó kọ òfin yìí, kì í ṣe òfin ènìyàn ni ẹni náà kọ̀, bí kò ṣe òfin Ọlọ́run ẹni tí ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ fún ni.


Ẹnìkan ṣoṣo tí ó jẹ àìkú, tí ń gbé inú ìmọ́lẹ̀ tí a kò lè súnmọ́, ẹni tí ènìyàn kan kò rí rí, tí a kò sì lè rí: ẹni tí ọlá àti agbára títí láé ń ṣe tirẹ̀. Àmín.


Ní ìgbà àtijọ́, Ọlọ́run bá àwọn baba ńlá wa sọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì ní ọ̀pọ̀ ìgbà àti ní onírúurú ọ̀nà,


Ọmọ tí í ṣe ìtànṣán ògo Ọlọ́run àti àwòrán òun tìkára rẹ̀, tí ó sì ń fi ọ̀rọ̀ agbára rẹ̀ mú ohun gbogbo dúró: Lẹ́yìn tí ó ti ṣe ìwẹ̀nù ẹ̀ṣẹ̀ wa tan, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọláńlá ní òkè.


Ṣùgbọ́n pàápàá àwọn tí ó ń tọ ẹran-ara lẹ́yìn nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ìwà èérí, tí wọ́n sì ń gan àwọn ìjòyè. Àwọn ọ̀dájú àti agbéraga, wọn kò bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí àwọn ẹni ògo.


Bákan náà ni àwọn wọ̀nyí ń sọ ara wọn di èérí nínú àlá wọn, wọ́n ń gan ìjòyè, wọn sì ń sọ̀rọ̀ búburú sí àwọn ọlọ́lá.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan