Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 12:5 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Nígbà náà ni Olúwa sọ̀kalẹ̀ nínú ọ̀wọ́n ìkùùkuu, ó sì dúró ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́, ó ké sí Aaroni àti Miriamu. Àwọn méjèèjì sì bọ́ síwájú,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 OLUWA sì dúró ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ ninu ọ̀wọ̀n ìkùukùu, ó sì pe Aaroni ati Miriamu, àwọn mejeeji sì jáde siwaju.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 OLUWA si sọkalẹ wá ninu ọwọ̀n awọsanma, o si duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ na, o si pè Aaroni ati Miriamu: awọn mejeji si jade wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 12:5
6 Iomraidhean Croise  

Ó sọ̀rọ̀ sí wọn nínú ọ̀wọ́n àwọsánmọ̀, wọ́n pa ẹ̀rí rẹ̀ mọ́ àti ìlànà tí ó fún wọn.


Olúwa sọ fún Mose pé, “Èmi yóò tọ̀ ọ́ wá nínú ìkùùkuu ṣíṣú dudu, kí àwọn ènìyàn lè gbọ́ ohùn mi nígbà ti mo bá ń bá ọ sọ̀rọ̀, kí wọn kí ó lè máa gbà ọ́ gbọ́.” Nígbà náà ni Mose sọ ohun tí àwọn ènìyàn wí fún Olúwa.


Nígbà náà ni Olúwa sọ̀kalẹ̀ nínú àwọsánmọ̀, ó sì dúró níbẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì pòkìkí orúkọ Olúwa.


Nítorí náà àwọsánmọ̀ Olúwa wà lórí àgọ́ ní ọ̀sán, iná sì wà nínú àwọsánmọ̀ ní alẹ́, ní ojú gbogbo ilé Israẹli ní gbogbo ìrìnàjò wọn.


Nígbà náà ni Olúwa sọ̀kalẹ̀ nínú ìkùùkuu ó sì bá wọn sọ̀rọ̀, ó sì mú lára Ẹ̀mí tó wà lára Mose sí ara àwọn àádọ́rin (70) àgbàgbà náà, Ó sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí Ẹ̀mí náà bà lé wọn, wọ́n sọtẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí wọn kò sọtẹ́lẹ̀ mọ́.


Lẹ́ẹ̀kan náà ni Olúwa sọ fún Mose, Aaroni àti Miriamu pé, “Ẹ̀yin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, jáde wá sínú àgọ́ ìpàdé.” Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì jáde síta.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan