Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 12:16 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 Lẹ́yìn èyí, àwọn ènìyàn kúrò ní Haserotu, wọ́n sì pa ibùdó sí Aginjù Parani.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

16 Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣí kúrò ni Haserotu, wọ́n sì pa àgọ́ wọn sí aṣálẹ̀ Parani.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

16 Lẹhin eyinì li awọn enia si ṣí kuro ni Haserotu, nwọn si dó si ijù Parani.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 12:16
10 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí ó ń gbé ni aginjù ní Parani, ìyá rẹ̀ fẹ́ ìyàwó fún un láti ilẹ̀ Ejibiti wá.


Ọlọ́run yóò wa láti Temani, ibi mímọ́ jùlọ láti Òkè Parani ògo rẹ̀ sí bo àwọn ọ̀run, ilé ayé sì kún fún ìyìn rẹ


Àwọn ọmọ Israẹli sì gbéra kúrò ní aginjù Sinai wọ́n sì rin ìrìnàjò wọn káàkiri títí tí ìkùùkuu fi dúró sí aginjù Parani.


Àwọn ènìyàn yòókù sì gbéra láti Kibirotu-Hattaafa lọ pa ibùdó sí Haserotu wọ́n sì dúró níbẹ̀.


Miriamu sì dúró sí ẹ̀yìn ibùdó fún ọjọ́ méje, àwọn ènìyàn kò sì tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò wọn títí tí Miriamu fi wọ inú ibùdó padà.


Olúwa sọ fún Mose pé,


Wọ́n padà wá bá Mose àti Aaroni àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ní ijù Kadeṣi Parani. Wọ́n mú ìròyìn wá fún wọn àti fún gbogbo ìjọ ènìyàn, wọ́n fi èso ilẹ̀ náà hàn wọ́n.


Mose sì rán wọn jáde láti Aginjù Parani gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa. Gbogbo wọn jẹ́ olórí àwọn ènìyàn Israẹli.


Wọ́n kúrò ní Haserotu wọ́n sì pàgọ́ ní Ritma.


Samuẹli sì kú; gbogbo ènìyàn Israẹli sì kó ara wọn jọ, wọ́n sì sọkún rẹ̀ wọ́n sì sin ín nínú ilé rẹ̀ ní Rama. Dafidi sì dìde, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ijù Parani.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan