Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 12:10 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Nígbà tí ìkùùkuu kúrò lórí àgọ́ lójijì ni Miriamu di adẹ́tẹ̀, ó funfun bí i yìnyín. Aaroni sì padà wo Miriamu ó sì rí i pé ó ti di adẹ́tẹ̀,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

10 Bí ọ̀wọ̀n ìkùukùu tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ ti gbéra sókè ni ẹ̀tẹ̀ bo Miriamu, ó sì funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Nígbà tí Aaroni wo Miriamu ó ri wí pé ó ti di adẹ́tẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 Awọsanma si lọ kuro lori Agọ́ na; si kiyesi i, Miriamu di adẹ̀tẹ, o fun bi òjo didì; Aaroni si wò Miriamu, si kiyesi i, o di adẹ̀tẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 12:10
13 Iomraidhean Croise  

Olúwa sì kọlu ọba náà pẹ̀lú ẹ̀tẹ̀, títí di ọjọ́ tí ó kú, ó sì ń gbé ní ilé ọ̀tọ̀. Jotamu, ọmọ ọba sì tọ́jú ààfin, ó sì ń darí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà.


Ẹ̀tẹ̀ Naamani yóò lẹ̀ mọ́ ọ àti sí irú-ọmọ rẹ títí láé.” Nígbà náà Gehasi kúrò níwájú Eliṣa, ó sì di adẹ́tẹ̀, ó sì funfun gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ̀n òwú.


Nísinsin yìí àwọn ọkùnrin mẹ́rin kan wà pẹ̀lú ẹ̀tẹ̀ ní ẹnu àbáwọlé ibodè ìlú. Wọ́n wí fún olúkúlùkù pé, “kí ni ó dé tí àwa yóò fi jókòó síbí títí àwa yóò fi kú?


Ní ìgbà náà ni Olúwa wí pé, “Ti ọwọ́ rẹ bọ inú aṣọ ní igbá àyà rẹ̀.” Mose sì ti ọwọ́ rẹ̀ bọ inú aṣọ ní igbá àyà rẹ̀, ní ìgbà ti ó sì yọ ọ́ jáde, ọwọ́ rẹ̀ ti dẹ́tẹ̀, ó sì ti funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú.


Bí wọ́n tilẹ̀ tọ́ ọmọ dàgbà. Èmi yóò mú wọn ṣọ̀fọ̀ lórí gbogbo wọn Ègbé ni fún wọn, nígbà tí mo yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn!


“Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọn ó lé ẹnikẹ́ni tó bá ní ẹ̀tẹ̀, ìtújáde ara ní oríṣìíríṣìí tàbí ẹni tó jẹ́ aláìmọ́ nípa fífọwọ́ kan òkú.


“Nígbà náà ni yóò sọ fún àwọn tí ọwọ́ òsì pé, ‘Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin ẹni ègún, sínú iná àìnípẹ̀kun tí a ti tọ́jú fún èṣù àti àwọn angẹli rẹ̀.


Rántí ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ṣe sí Miriamu lójú ọ̀nà lẹ́yìn ìgbà tí o jáde kúrò ní Ejibiti.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan