Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 12:1 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Miriamu àti Aaroni sọ̀rọ̀-òdì sí Mose nítorí pé ó fẹ́ obìnrin ará Etiopia.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Miriamu ati Aaroni sọ̀rọ̀ òdì sí Mose nítorí pé ó fẹ́ ọmọbinrin ará Kuṣi ní iyawo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 A TI Miriamu ati Aaroni sọ̀rọ òdi si Mose nitori obinrin ara Etiopia ti o gbé ni iyawo: nitoripe o gbé obinrin ara Etiopia kan ni iyawo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 12:1
19 Iomraidhean Croise  

Èmi yóò mú ọ búra lórúkọ Olúwa Ọlọ́run ọ̀run àti ayé, pé, ìwọ kì yóò fẹ́ aya fún ọmọ mi nínú àwọn ọmọbìnrin ará Kenaani, láàrín àwọn ẹni tí èmi ń gbé.


Olúwa mi sì ti mú mi búra wí pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fẹ́ aya fún ọmọ mi, láàrín àwọn ọmọbìnrin Kenaani, ní ilẹ̀ ibi tí èmi ń gbé,


Nígbà náà ni Rebeka wí fún Isaaki pé, “Ayé sì sú mi nítorí àwọn ọmọbìnrin Hiti wọ̀nyí. Bí Jakọbu bá fẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin Hiti wọ̀nyí, ó kúkú sàn kí n má wà láààyè.”


Farao sì sọ Josẹfu ní orúkọ yìí: Safenati-Panea èyí tí ó túmọ̀ sí, (ẹni tí ó ni agbára ikú àti ìyè ní ìkáwọ́ bí òrìṣà), Ó sì fun un ní Asenati ọmọ Potifẹra, alábojútó òrìṣà Oni, gẹ́gẹ́ bí aya. Josẹfu sì rin gbogbo ilẹ̀ Ejibiti já.


Ó sì ṣe, àlùfáà Midiani kan ni àwọn ọmọbìnrin méje, wọn sì wá láti pọn omi kún ọpọ́n ìmumi fún ẹran ọ̀sìn baba wọn.


Mose gbà láti dúró lọ́dọ̀ ọkùnrin náà, ẹni tí o fi Sippora, ọmọbìnrin rẹ̀ fún Mose láti fi ṣe aya.


Nígbà tí ìwọ bá yàn nínú àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin rẹ ní ìyàwó, àwọn ọmọbìnrin wọ̀nyí yóò ṣe àgbèrè tọ òrìṣà wọn, wọn yóò sì mú kí àwọn ọmọkùnrin yín náà ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.


Kò gbọdọ̀ fẹ́ opó tàbí ẹni tí a kọ̀sílẹ̀ tàbí obìnrin tí ó ti fi àgbèrè ba ara rẹ̀ jẹ́, ṣùgbọ́n kí ó fẹ́ obìnrin tí kò mọ ọkùnrin rí, láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.


Kò sí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn tó rí ògo mi àti àwọn iṣẹ́ ààmì tí mo ṣe ní ilẹ̀ Ejibiti àti nínú aginjù ṣùgbọ́n tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí mi, tí wọn sì dán mi wò ní ìgbà mẹ́wàá yìí,


Wọ́n sì dìde sí Mose, pẹ̀lú àádọ́tà-lé-nígba (250) ọkùnrin nínú àwọn ọmọ Israẹli, ìjòyè nínú ìjọ, àwọn olórúkọ nínú àjọ, àwọn ọkùnrin olókìkí.


Orúkọ aya Amramu sì ń jẹ́ Jokebedi, ọmọbìnrin Lefi, tí ìyá rẹ̀ bí fún Lefi ní Ejibiti. Òun sì bí Aaroni, Mose, àti Miriamu arábìnrin wọn fún Amramu.


Ará ilé ènìyàn ni yóò sì máa ṣe ọ̀tá rẹ̀.’


Ó sì fún ni èsì pé, “Ta ni ìyá mi? Ta ni àwọn arákùnrin mi?”


Ẹ rántí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fún yín pé, ‘Ọmọ ọ̀dọ̀ kò tóbi ju olúwa rẹ̀ lọ.’ Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọ́n ó ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú: bí wọ́n bá ti pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, wọ́n ó sì pa tiyín mọ́ pẹ̀lú.


Nítorí pé àwọn arákùnrin rẹ̀ pàápàá kò tilẹ̀ gbà á gbọ́.


Ǹjẹ́ mo ha di ọ̀tá yín nítorí mo sọ òtítọ́ fún yín bí?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan