Numeri 11:8 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní8 Àwọn ènìyàn náà ń lọ káàkiri láti kó o, wọn ó lọ̀ ọ́ lórí ọlọ tàbí kí wọ́n gún un nínú odó. Wọ́n le sè é nínú ìkòkò tàbí kí wọn ó fi ṣe àkàrà, adùn rẹ̀ yóò sì dàbí adùn ohun tí a fi òróró ṣe. Faic an caibideilYoruba Bible8 Àwọn eniyan náà a máa lọ kó wọn láàárọ̀, wọn á lọ̀ ọ́ tabi kí wọn gún un lódó láti fi ṣe ìyẹ̀fun. Wọn á sè é ninu ìkòkò, wọn á fi ṣe bíi àkàrà, adùn rẹ̀ sì dàbí ti àkàrà dídùn tí a fi òróró olifi dín. Faic an caibideilBibeli Mimọ8 Awọn enia na a ma lọ kakiri, nwọn a si kó o, nwọn a si lọ̀ ọ ninu ọlọ, tabi nwọn a si gún u ninu odó, nwọn a si sè e ninu ìkoko, nwọn a si fi din àkara: itọwò rẹ̀ si ri bi itọwò àkara oróro. Faic an caibideil |