Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 11:4 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn aláìníláárí tó wà láàrín àwọn ọmọ Israẹli pẹ̀lú ọkàn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn fi ìtara béèrè fún oúnjẹ mìíràn, àwọn ọmọ Israẹli náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í sọkún wí pé, “Bí i pé kí á rí ẹran jẹ báyìí!

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 Àwọn àjèjì tí wọ́n wà láàrin àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí kùn, pé àwọn kò rí ẹran jẹ bí ìgbà tí àwọn wà ní Ijipti. Àwọn ọmọ Israẹli pàápàá bẹ̀rẹ̀ sí sọkún àìrẹ́ran jẹ. Wọ́n ń sọ pé, “Ó mà ṣe o, a kò rí ẹran jẹ!

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Awọn adalú ọ̀pọ enia ti o wà pẹlu wọn ṣe ifẹkufẹ: awọn ọmọ Israeli pẹlu si tun sọkun wipe, Tani yio fun wa li ẹran jẹ?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 11:4
16 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí àwọn ènìyàn gbọ́ òfin yìí, wọ́n yọ gbogbo àwọn àjèjì ènìyàn tí ó darapọ̀ mọ́ wọn kúrò láàrín àwọn Israẹli.


Nínú aginjù ni wọ́n tí ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ nínú aṣálẹ̀, wọ́n dán Ọlọ́run wò


Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn mìíràn ni ó bá wọ́n lọ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹran ọ̀sìn, agbo àgùntàn àti agbo màlúù.


“Èmi ti gbọ́ kíkùn àwọn ọmọ Israẹli. Sọ fun wọn, ‘Ní àṣálẹ́, ẹ̀yin yóò jẹ ẹran, àti ni òwúrọ̀ ni ẹ̀yin yóò jẹ oúnjẹ. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ”


Àwọn ọmọ Israẹli wí fún wọn pé, “Àwa ìbá ti ọwọ́ Olúwa kú ni Ejibiti! Níbi tí àwa ti jókòó ti ìkòkò ẹran ti a sì ń jẹ ohun gbogbo tí a fẹ́ ni àjẹyó, ṣùgbọ́n ẹ̀yin mú wa wá sí inú ijù yìí láti fi ebi pa wá tí a ó fi kú.”


Àti pé bí ẹ̀yin bá wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò lọ gbé ní Ejibiti; níbi tí àwa kì yóò rí ìró ogunkógun, tí a kì yóò sì gbọ́ ìró fèrè, tí ebi oúnjẹ kì yóò sì pa wá, níbẹ̀ ni àwa ó sì máa gbé,’


“Sọ fún àwọn ènìyàn náà pé: ‘Ẹ ya ara yín sí mímọ́ ní ìmúrasílẹ̀ fún ọ̀la, ẹ ó sì jẹ ẹran. Nítorí pé Olúwa ti gbọ́ igbe ẹkún yín, èyí tí ẹ sun pé, “Ìbá ṣe pé a lè rí ẹran jẹ ni! Ó sàn fún wa ní Ejibiti jù báyìí lọ!” Nítorí náà ni Olúwa yóò fi fún yín ní ẹran, ẹ ó sì jẹ ẹ́.


Gbogbo ìjọ ènìyàn sì gbóhùn sókè, wọ́n sì sọkún ní òru ọjọ́ náà.


Kò sí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn tó rí ògo mi àti àwọn iṣẹ́ ààmì tí mo ṣe ní ilẹ̀ Ejibiti àti nínú aginjù ṣùgbọ́n tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí mi, tí wọn sì dán mi wò ní ìgbà mẹ́wàá yìí,


Kò ha tó gẹ́ẹ́ pé o ti mú wa jáde láti ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin láti pa wá sínú aginjù yìí? O tún wá fẹ́ sọ ara rẹ di olúwa lé wa lórí bí?


Ṣùgbọ́n ẹ gbé Jesu Kristi Olúwa wọ̀, kí ẹ má sì pèsè fún ara, láti máa mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣẹ.


Àwọn nǹkan wọ̀nyí sì jásí àpẹẹrẹ fún àwa, kí a má ṣe ní ìfẹ́ sí àwọn ohun búburú gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn yìí ṣe ní ìfẹ́ si.


Kí a má tàn yín jẹ́, “Ẹgbẹ́ búburú bá ìwà rere jẹ́.”


Ẹ̀yin tún mú Olúwa bínú ní Tabera, Massa àti ní Kibirotu-Hattaafa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan