Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 11:21 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

21 Ṣùgbọ́n Mose sọ pé, “Mo wà láàrín ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ènìyàn (600,000) ni ìrìnkiri, ó sì sọ pé, ‘Èmi ó fún wọn ní ẹran láti jẹ fún oṣù kan gbáko!’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

21 Mose sì sọ fún OLUWA pé, “Àwọn tí wọn tó ogun jà nìkan ninu àwọn eniyan tí mò ń ṣe àkóso wọn yìí jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ (600,000) o sì wí pé o óo fún wọn ní ẹran jẹ fún oṣù kan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

21 Mose si wipe, Awọn enia na, lãrin awọn ẹniti emi wà, jẹ́ ọgbọ̀n ọkẹ ẹlẹsẹ̀; iwọ si wipe, Emi o fun wọn li ẹran, ki nwọn ki o le ma jẹ li oṣù kan tọ̀tọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 11:21
9 Iomraidhean Croise  

“Èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá Èmi yóò sì bùkún fún ọ. Èmi yóò sọ orúkọ rẹ di ńlá, ìbùkún ni ìwọ yóò sì jásí.


Àwọn ọmọ Israẹli sì rìn láti Ramesesi lọ sí Sukkoti. Àwọn ọkùnrin tó ń fi ẹsẹ̀ rìn tó ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ (600,000) ni iye láìka àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé.


ààbọ̀ ṣékélì kan ní orí ẹnìkọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́, lórí olúkúlùkù ẹni tí ó ti kọjá tí a ti kà, láti ẹni ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, àròpọ̀ wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n-ọ̀kẹ́-lé-ẹgbẹ̀ta-dínlógún ó-lé-àádọ́jọ ọkùnrin (603,550).


Àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó-lé-egbéjì-dínlógún-dínàádọ́ta, (603,550).


Níbo ni n ó ti rí ẹran fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí? Nítorí wọ́n ń sọkún sí mi pé, ‘Fún wa lẹ́ran jẹ́!’


Ṣùgbọ́n fún odidi oṣù kan: títí tí ẹran náà yóò fi máa yọ ní imú yín, tí yóò sì sú yín: nítorí pé ẹ ti kẹ́gàn Olúwa tí ó wà láàrín yín, ẹ sì ti sọkún fún un wí pé, “Kí ló dé tí a fi kúrò ní Ejibiti gan an?” ’ ”


Ǹjẹ́ bí a tilẹ̀ pa àgbò ẹran àti ọmọ ẹran, yóò ha tó wọn bí? Tàbí bí a tilẹ̀ pa gbogbo ẹja inú omi fún wọn, yóò wa tó bí?”


Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n kà nípa ìdílé wọn. Gbogbo àwọn tó wà ní ibùdó, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó-lé-egbéjì-dínlógún-dínàádọ́ta (603,550).


Àpapọ̀ iye tí a kà nínú àwọn ọmọ Israẹli jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó-lé-ẹgbẹ̀sán ó-dínàádọ́rin (601,730).


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan