Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 11:11 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 Mose sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa pé, “Kí ló dé tí o fi mú wàhálà yìí bá ìránṣẹ́ rẹ? Kí ni mo ṣe tí n kò fi tẹ ọ lọ́rùn tí ìwọ fi di ẹrù àwọn ènìyàn wọ̀nyí lé mi lórí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

11 Mose bá wí fún OLUWA pé, “Kí ló dé tí o ṣe mí báyìí? Kí ló dé tí n kò rí ojurere rẹ, tí o sì di ẹrù gbogbo àwọn eniyan wọnyi rù mí?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

11 Mose si wi fun OLUWA pe, Nitori kini iwọ fi npọ́n iranṣẹ rẹ loju? nitori kili emi kò si ṣe ri ore-ọfẹ li oju rẹ, ti iwọ fi dì ẹrù gbogbo enia yi lé mi?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 11:11
16 Iomraidhean Croise  

Èmi yóò wí fún Ọlọ́run pé: má ṣe dá mi lẹ́bi; fihàn mí nítorí ìdí ohun tí ìwọ fi ń bá mi jà.


Olúwa, ìbá ṣe pé kí ìwọ máa sàmì ẹ̀ṣẹ̀, Olúwa, tá ni ìbá dúró.


Má ṣe mú ìránṣẹ́ rẹ wá sí ìdájọ́, nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wà láààyè tí ó ṣe òdodo níwájú rẹ.


Nígbà náà ni Mose gbé ohùn rẹ̀ sókè sí Olúwa pé; “Kí ni kí èmi kí ó ṣe fún àwọn ènìyàn yìí? Wọ́n múra tan láti sọ mi ni òkúta.”


Mose padà tọ Olúwa lọ, ó sì wí pé, “Olúwa, èéṣe tí ìwọ fi mú ìyọnu wá sí orí àwọn ènìyàn wọ̀nyí? Ṣe torí èyí ni ìwọ fi rán mi?


Háà! Ó ṣe tí ìyá mi bí mi: ọkùnrin tí gbogbo ilẹ̀ dojúkọ tí wọ́n sì bá jà, èmi kò wínni, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò yá lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni síbẹ̀, gbogbo ènìyàn ló ń fi mí ré.


Èéṣe tí ìrora mi kò lópin, tí ọgbẹ́ mi kò sì ṣe é wòsàn? Ní òtítọ́ ìwọ yóò dàbí kànga ẹ̀tàn sí mi, gẹ́gẹ́ bí ìsun tó kọ̀ tí kò sun?


“Ẹ̀yin ti wí pé, ‘Asán ni láti sin Ọlọ́run. Kí ni àwa jẹ ní èrè, nígbà tí àwa ti pa ìlànà rẹ mọ́, tí àwa sì ń rìn kiri bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ní iwájú Olúwa àwọn ọmọ-ogun?


Mose sì gbọ́ tí àwọn ènìyàn ń sọkún ní gbogbo ìdílé wọn, oníkálùkù ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ tirẹ̀. Olúwa sì bínú gidigidi. Inú Mose sì bàjẹ́ pẹ̀lú.


Bí ó bá sì ṣe pé báyìí ni ìwọ ó ṣe máa ṣe fún mi, kúkú pa mí báyìí, tí mo bá ti bá ojúrere rẹ pàdé—kí ojú mi má ba à rí ìparun mi.”


Pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí tí ó jẹ́ tí òde, ọ̀pọ̀ ni èyí tí ń wọn n dúró tì mí lójoojúmọ́, àní àníyàn fún gbogbo ìjọ.


Báwo ni èmi nìkan ṣe lè máa ru àjàgà àti ìṣòro yín àti èdè-àìyedè yín?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan