Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 10:14 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

14 Àwọn ìpín ti ibùdó Juda ló kọ́kọ́ gbéra tẹ̀lé wọn lábẹ́ ogun wọn Nahiṣoni ọmọ Amminadabu ni ọ̀gágun wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

14 Àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ ọ̀págun ẹ̀yà Juda ni wọ́n kọ́kọ́ ṣí, wọ́n tò ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Naṣoni ọmọ Aminadabu ni olórí wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

14 Ọpágun ibudó awọn ọmọ Juda si kọ́ ṣí gẹgẹ bi ogun wọn: olori ogun rẹ̀ si ni Naṣoni ọmọ Amminadabu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 10:14
10 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí Israẹli sì ń gbé ní ibẹ̀, Reubeni wọlé tọ Biliha, àlè (ìyàwó tí a kò fi owó fẹ́ lọ́wọ́ àwọn òbí rẹ̀) baba rẹ̀ lọ, ó sì bá a lòpọ̀, Israẹli sì gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. Jakọbu sì bí ọmọkùnrin méjìlá:


Àwọn ọmọ Lea: Reubeni tí í ṣe àkọ́bí Jakọbu, Simeoni, Lefi, Juda, Isakari àti Sebuluni.


“Juda, àwọn arákùnrin rẹ yóò yìn ọ, ọwọ́ rẹ yóò wà ní ọrùn àwọn ọ̀tá rẹ, àwọn ọmọkùnrin baba rẹ yóò foríbalẹ̀ fún ọ.


“Orúkọ àwọn ọkùnrin tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ nìyí: “Láti ọ̀dọ̀ Reubeni, Elisuri ọmọ Ṣedeuri;


Láti ọ̀dọ̀ Juda, Nahiṣoni ọmọ Amminadabu;


Netaneli ọmọ Ṣuari ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Isakari;


Nígbà tí o bá fun ìpè ìdágìrì, àwọn ẹ̀yà tó pa ibùdó sí ìhà ìlà-oòrùn ni yóò gbéra.


Ẹni tí ó mú ọrẹ tirẹ̀ wá ní ọjọ́ kìn-ín-ní Nahiṣoni ọmọ Amminadabu láti inú ẹ̀yà Juda.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan