Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 1:53 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

53 Àwọn ọmọ Lefi yóò jẹ́ alábojútó àti olùtọ́jú àgọ́ ẹ̀rí náà, kí ìbínú má ba à sí lára ìjọ àwọn ọmọ Israẹli; kí àwọn ọmọ Lefi sì máa ṣe ìtọ́jú àgọ́ ẹ̀rí náà.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

53 Ṣugbọn àwọn ọmọ Lefi ni kí wọ́n pàgọ́ yí Àgọ́-Ẹ̀rí ká, kí àwọn tí kì í ṣe ọmọ Lefi má baà súnmọ́ Àgọ́ náà, kí n má baà bínú sí àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ọmọ Lefi ni yóo máa ṣe ìtọ́jú Àgọ́ Ẹ̀rí náà.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

53 Ṣugbọn awọn ọmọ Lefi ni ki o dó yi agọ́ erí na ká, ki ibinu ki o má ba si lara ijọ awọn ọmọ Israeli: ki awọn ọmọ Lefi ki o si ma ṣe itọju agọ́ ẹrí na.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 1:53
26 Iomraidhean Croise  

Bẹ́ẹ̀ ni nígbà náà, àwọn ọmọ Lefi gbé ìgbékalẹ̀ jáde fún ìpàdé àgọ́, fún ibi mímọ́ àti, lábẹ́ àwọn arákùnrin àwọn ọmọ Aaroni fún ìsìn ilé Olúwa.


“Ní ti àwa, Olúwa ni Ọlọ́run wa, àwa kò sì ti ì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Àwọn àlùfáà tí ó ń sin Olúwa jẹ́ àwọn ọmọ Aaroni àwọn ará Lefi sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́.


Ní àràárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́, wọ́n gbé ẹbọ sísun àti tùràrí olóòórùn dídùn síwájú Olúwa. Wọ́n gbé àkàrà jáde sórí tábìlì àsè mímọ́, wọ́n sì tan iná sí àwọn fìtílà lórí ìdúró ọ̀pá fìtílà wúrà ní gbogbo ìrọ̀lẹ́. A ń pa àṣẹ Olúwa Ọlọ́run wa mọ́. Ṣùgbọ́n ìwọ ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀.


Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Alágbára wí ní ti àwọn wòlíì: “Èmi yóò mú wọn jẹ oúnjẹ kíkorò, wọn yóò mu omi májèlé nítorí láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì Jerusalẹmu ni àìwà-bí-Ọlọ́run ti tàn ká gbogbo ilẹ̀.”


Àwọn wòlíì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké, àwọn àlùfáà sì ń ṣe àkóso pẹ̀lú àṣẹ ara wọn, àwọn ènìyàn mi sì ní ìfẹ́ sí èyí, kí ni ẹ̀yin yóò ṣe ní òpin?


Mose sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù, Eleasari àti Itamari pé, “ẹ má ṣe ṣọ̀fọ̀ nípa ṣíṣe aláìtọ́jú irun yín tàbí kí ẹ ṣí orí yín sílẹ̀, ẹ kò sì gbọdọ̀ ya aṣọ, bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó kùú, Olúwa yóò sì bínú sí gbogbo ìjọ ènìyàn. Ṣùgbọ́n àwọn ẹbí yín, àti gbogbo ilé Israẹli le è ṣọ̀fọ̀ lórí àwọn tí Olúwa fi iná parun.


Dípò èyí yan àwọn ọmọ Lefi láti jẹ́ alábojútó àgọ́ ẹ̀rí, lórí gbogbo ohun èlò àti ohun gbogbo tó jẹ́ ti àgọ́ ẹ̀rí. Àwọn ni yóò máa gbé àgọ́ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, wọn ó máa mójútó o, kí wọn ó sì máa pàgọ́ yí i ká.


Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.


Mose sì sọ fún Aaroni pé, “Mú àwo tùràrí, kí o fi iná sí i lórí pẹpẹ, fi tùràrí sínú rẹ̀, kí o sì tètè mu lọ sí àárín ìjọ ènìyàn láti ṣe ètùtù fún wọn nítorí pé ìbínú Olúwa ti jáde, àjàkálẹ̀-ààrùn sì ti bẹ̀rẹ̀.”


Kò ha tọ́ fún yín pé Ọlọ́run Israẹli ti yà yín sọ́tọ̀ lára ìjọ Israẹli yòókù, tó sì mú yín súnmọ́ ara rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ Olúwa àti láti dúró ṣiṣẹ́ ìsìn níwájú àwọn ènìyàn?


Mose sì fi ọ̀pá wọ̀nyí lélẹ̀ níwájú Olúwa nínú àgọ́ ẹ̀rí.


Nígbà náà ni àwọn ọmọ Lefi Àti àgọ́ ìpàdé yóò tẹ̀síwájú láàrín ibùdó àwọn ènìyàn, wọn yóò tẹ̀síwájú ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe pa ibùdó, olúkúlùkù láààyè rẹ̀, àti lábẹ́ ọ̀págun rẹ̀.


Àwọn ìdílé Gerṣoni yóò pa ibùdó sí ìhà ìwọ̀-oòrùn lẹ́yìn àgọ́.


Àwọn ìdílé Kohati yóò pa ibùdó wọn sí ìhà gúúsù ní ẹ̀gbẹ́ àgọ́.


Olórí àwọn ìdílé ìran Merari ni Ṣurieli ọmọ Abihaili. Wọn yóò pa ibùdó wọn sí ìhà àríwá àgọ́.


Mose àti Aaroni pẹ̀lú àwọn ọmọ yóò pa àgọ́ ní ìdojúkọ ìwọ̀-oòrùn níwájú àgọ́ ìpàdé. Iṣẹ́ wọn ni láti máa mójútó iṣẹ́ ìsìn ibi mímọ́ àti láti máa ṣiṣẹ́ ìsìn fún àwọn ọmọ Israẹli. Àlejò tó bá súnmọ́ ibi mímọ́ yàtọ̀ sí àwọn tí a yàn, pípa ni kí ẹ pa á.


Lára ààbọ̀ ti Israẹli, yan ọ̀kan kúrò nínú àádọ́ta, (50) yálà ènìyàn, ẹran ọ̀sìn, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn, ewúrẹ́ tàbí ẹ̀yà ẹranko mìíràn. Kó wọn fún àwọn Lefi, tí ó dúró fún olùtọ́jú àgọ́ Olúwa.”


Lára ààbọ̀ ti àwọn ọmọ Israẹli, Mose yan ọ̀kan lára àádọ́ta (50) ènìyàn àti ẹranko gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún un. Ó sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ Lefi, tí ń ṣe olùtọ́jú àgọ́ Olúwa.


Nínú Israẹli, mo fi àwọn ọmọ Lefi fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn láti máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé fun àwọn ọmọ Israẹli àti láti máa ṣe ètùtù fún wọn kí àjàkálẹ̀-ààrùn má ba à kọlu àwọn ọmọ Israẹli nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ ibi mímọ́.”


Wàásù ọ̀rọ̀ náà, ṣe àìsimi ní àkókò tí ó wọ̀, àti àkókò ti kò wọ̀; bá ni wí, ṣe ìtọ́ni, gbani níyànjú pẹ̀lú ìpamọ́ra àti ẹ̀kọ́ gbogbo.


Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kọlu díẹ̀ lára àwọn ọkùnrin Beti-Ṣemeṣi, ó pa àádọ́rin wọn, nítorí wọ́n ti wo inú àpótí ẹ̀rí Olúwa. Àwọn ènìyàn ṣọ̀fọ̀ nítorí àjálù ńlá tí Olúwa fi bá ọ̀pọ̀ wọn jà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan