Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 1:46 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

46 Àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó-lé-egbéjì-dínlógún-dínàádọ́ta, (603,550).

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

46 jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ eniyan o le egbejidinlogun ó dín aadọta (603,550).

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

46 Ani gbogbo awọn ti a kà o jẹ́ ọgbọ̀n ọkẹ enia o le egbejidilogun din ãdọta.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 1:46
24 Iomraidhean Croise  

“Èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá Èmi yóò sì bùkún fún ọ. Èmi yóò sọ orúkọ rẹ di ńlá, ìbùkún ni ìwọ yóò sì jásí.


Èmi yóò mú kí irú-ọmọ rẹ kí ó pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ó bá ṣe pé ẹnikẹ́ni bá le è ka erùpẹ̀ ilẹ̀, nígbà náà ni yóò tó lè ka irú-ọmọ rẹ.


Olúwa sì mú Abramu jáde sí ìta ó sì wí fún un pé, “Gbé ojú sókè sí ọ̀run kí o sì ka àwọn ìràwọ̀ bí ó bá ṣe pé ìwọ le è kà wọ́n.” Ó sì wí fun un pé, “Nítorí náà, báyìí ni irú-ọmọ rẹ yóò rí.”


Èmi yóò mú ọ bí si lọ́pọ̀lọpọ̀, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ni èmi yóò sì mú ti ara rẹ jáde wá, àwọn ọba pẹ̀lú yóò sì ti inú rẹ jáde.


Nítòótọ́, ní bíbùkún èmi ó bùkún fún ọ, àti ní bíbísí èmi ó sì mú ọ bí sí i bí i ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti bí iyanrìn etí Òkun. Irú-ọmọ rẹ yóò sì gba ẹnu ibodè àwọn ọ̀tá wọn,


Máa ṣe àtìpó ní ilẹ̀ yìí fún ìgbà díẹ̀, èmi ó sì wà pẹ̀lú rẹ, Èmi yóò sì bùkún fún ọ. Nítorí ìwọ àti irú-ọmọ rẹ ni èmi yóò fi gbogbo àwọn ilẹ̀ wọ̀nyí fún, èmi yóò sì fi ìdí ìbúra tí mo ṣe fún Abrahamu baba rẹ múlẹ̀.


Ìran rẹ yóò pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, ìwọ yóò sì tànkálẹ̀ dé ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn, àti dé gúúsù àti àríwá. A ó sì bùkún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé nípasẹ̀ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ.


Joabu sì fi iye tí àwọn ènìyàn náà jásí lé ọba lọ́wọ́: ó sì jẹ́ òjì ọ̀kẹ́ ọkùnrin alágbára ní Israẹli, àwọn onídà: àwọn ọkùnrin Juda sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn.


Àwọn ènìyàn Juda àti ti Israẹli pọ̀ gẹ́gẹ́ bí iyanrìn tí ń bẹ ní etí Òkun; wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, wọ́n sì ń yọ ayọ̀.


Joabu sì fi àpapọ̀ iye àwọn ènìyàn náà fún Dafidi. Ní gbogbo Israẹli, ó sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún àti ọ̀kẹ́ márùn-ún ènìyàn (1,100,000) tí ń kọ́ idà, Juda sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́tàlélógún lé ẹgbàárùn-ún ọkùnrin tí ń kọ́ idà.


Abijah lọ sí ojú ogun pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun ogún ọ̀kẹ́ (40,000) ọkùnrin alágbára, Jeroboamu kó ogun jọ pẹ̀lú ogójì ọ̀kẹ́ (8,000) ọ̀wọ́ ogun tí ó lágbára.


Àwọn ọmọ Israẹli sì rìn láti Ramesesi lọ sí Sukkoti. Àwọn ọkùnrin tó ń fi ẹsẹ̀ rìn tó ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ (600,000) ni iye láìka àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé.


ààbọ̀ ṣékélì kan ní orí ẹnìkọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́, lórí olúkúlùkù ẹni tí ó ti kọjá tí a ti kà, láti ẹni ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, àròpọ̀ wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n-ọ̀kẹ́-lé-ẹgbẹ̀ta-dínlógún ó-lé-àádọ́jọ ọkùnrin (603,550).


Gbogbo ọmọkùnrin Israẹli tó jẹ́ ọmọ ogún ọdún (20) sókè, tó sì lè lọ sójú ogun ni wọ́n kà gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.


Ṣùgbọ́n Mose sọ pé, “Mo wà láàrín ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ènìyàn (600,000) ni ìrìnkiri, ó sì sọ pé, ‘Èmi ó fún wọn ní ẹran láti jẹ fún oṣù kan gbáko!’


Nínú aginjù yìí ni ẹ ó kú sí, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ kùn láti ọmọ ogún ọdún ó lé àní gbogbo ẹ̀yin tí a kà.


Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n kà nípa ìdílé wọn. Gbogbo àwọn tó wà ní ibùdó, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó-lé-egbéjì-dínlógún-dínàádọ́ta (603,550).


Ta ni ó lè ka eruku Jakọbu tàbí ka ìdámẹ́rin Israẹli? Jẹ́ kí èmi kú ikú olódodo, kí ìgbẹ̀yìn mi kí ó dà bí tirẹ̀!”


Àpapọ̀ iye tí a kà nínú àwọn ọmọ Israẹli jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó-lé-ẹgbẹ̀sán ó-dínàádọ́rin (601,730).


Àádọ́rin (70) péré ni àwọn baba ńlá a yín tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti, ṣùgbọ́n Olúwa Ọlọ́run yín ti mú un yín pọ̀ sí i ní iye bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan